You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹní bá fẹ́ ra ìbò, tí ìwọ náà sì fẹ́ ta ìbò rẹ se'bẹ̀ l'Osun, ìbéèrè tó yẹ kóo kọ́kọ́ bií rèé - Adarí INEC Osun
Adari ajọ INEC nipinlẹ Osun, Ọjọgbọn Abdulganiyu Raji ba BBc Yoruba sọrọ ni igbaradi de eto idiibo gomina ti yoo waye ni ipinlẹ Osun lọjọ Satide ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Keje ọdun 2022.
Ninu ọrọ rẹ, Ọjọgbọn Raji ni "Abdulganiyu Raji ni tẹ́ẹ bá ni ká dìbò báyìí báyìí, INEC ti ṣetán torí àwọn a ti kọ ẹ̀kọ́ lára ìdìbò ọdún 2018 àti 2019".
O ni nigba ti awọn ṣe agbeyẹwo, awọn pe awọn tọrọ kan jọ, awọn si ti jọ ṣe awọn ilana ilọsiwaju fun apẹrẹ, "Aye idibo 753 la ti ni bayii eyi to pọ ju ti atijọ lọ".
Raji ṣalaye ohun to yẹ ki awọn ara ipinlẹ Osun ṣe bi awọn oloṣelu ba wa lati ra ibo wọn.
O tun ṣalaye awọn ofin to wa nikalẹ fun ẹnikẹni to ba ṣe ohun ti ko tọ lasiko idibo.