Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri Nàìjíríà
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Ẹyin oṣiṣẹ eti yin meloo? Ẹ tete lọ forukọ silẹ fun nọmba igbeluu ni kiakia

Ṣe iyẹn lo kan ni, ti mi o ba forukọ silẹ nkọ?

Ijọba ipinlẹ Kwara ni ko ni si owo oṣu ati ajẹmọnu fun oṣiṣẹ ti ko baa ṣe bẹẹ ninu oṣu kọkanla

Ha! Ha! Ki ni wọn fẹ fi iforukọsilẹ naa ṣe?

Kian si oju opo bbc.com/yoruba fun ẹkunrẹrẹ

Ẹ dakun ẹ dabọ ẹ fiye denu, ẹ dawọ ogun duro

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lo n parọwa si Israel ati Palestine

Pe ogun to n lọ ni Gaza n fa ọpọlọpọ inira

Ohun to wa lẹyin Ofa ju oje

Ki lo de to n sọrọ lowelowe?

Njẹ o mọ pe o ṣeeṣe kawọn fidio ibalopọ Baltasar Ebang Engoga to gba ori ayelujara lọsẹ meji sẹyin lọwọ oṣelu ninu?

Ṣi a mi ki n wo o

Iwadii BBC kan fi han pe gbigbe awọn fidio sori ayelujara ni nnkan ṣe pẹlu ta ni yoo di aarẹ ni Equitorial Guinea

Bawo lo ṣe jẹ?

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́