'Mo ṣì ń retí ọkọ mi lẹ́yìn ọdún kan tó ti wa ní àhámọ́'

'Mo ṣì ń retí ọkọ mi lẹ́yìn ọdún kan tó ti wa ní àhámọ́'

Àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Israel tí ikọ̀ Hamas ṣe ìkọlù sí ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni wọ́n ṣì ń ka àdánù wọn.

Yàtọ̀ sí àwọn èèyàn tí Hamas ṣekúpa lásìkò ìkọlù náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n jí gbé lọ.

Àwọn kan ti rí ìtúsílẹ̀, àwọn mìíràn ti kú, táwọn míì ṣì wà ní àhámọ́ ikọ̀ Hamas.

Lára àwọn tó ṣì ń ká àdánù tí wọ́n kojú lásìkò náà ni Batsheva táwọn Hamas ṣe ìkọlù sí ilé rẹ̀.

Wọ́n gbé ọmọ rẹ̀ kan, Eitan àti ọkọ rẹ̀, Ohad gbé lásìkò ìkọlù náà àmọ́ tí wọ́n tú ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tó lo ọjọ́ méjìléláàádọ́ta ní àhámọ́ wọn.

Batsheva ní òun gbọ́ ìró ìbọn àti àdó olóró ní agbègbè àti àyíká ilé àwọn lásìkò ìkọlù náà.

Ó ní níṣe ni òun sálọ láti lè dóòlà ẹ̀mí òun àti ọmọ òun.

Ní oṣù Kìíní ọdún yìí ni fídíò Ohad kan jáde pé ó farapa àmọ́ ó ṣì wà láyé àmọ́ àwọn agbéṣùmọ̀mí ní ó ti jáde láyé lásìkò ìkọlù Israel kan.

BBC kò lè fìdí èyí múlẹ̀.

Batsheva àti ẹbí rẹ̀ ní àwọn ṣì ń retí Ohad nílé àti pé ohun tó burú jùlọ fáwọn ni pé àwọn kò mọ̀ bóyá ó wà láyé tàbí kò sí mọ́.

"Aò lè tẹ̀síwájú pẹ̀lú ayé wa nítorí Ohad ṣì wà ní àhámọ́ àwọn ikọ̀ Hamas."