You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Ìjà ni mo là, tí mo fi pàdánù ọwọ́ mí kán"
Salisu Hussaini, ẹni ọdun mẹtalelogun, to n gbe ni Kano, jẹ ọkan lara awọn eeyan ti wọn ko le gbagbe ọdun 2022 nitori iriri buruku to ri nigba to n gbiyanju lati ṣe rere.
Lọdun 2022, lẹyin ti Salisu kuro nibi isẹ lo saayan lati pari ija laarin eeyan meji kan laimọ pe oun ni yoo jẹ iya to pọju.
“Mo ji laarọ ọjọ naa daada, n ko mọ pe irin ajo aye mi yoo yipada lọjọ naa.”
“Mo lo gbogbo akoko mi ni sọọbu telọ mi, nigba ti mo kuro ni sọọbu ni bi ago mẹsan alẹ, mo kọkọ tẹle ọga mi lọ jisẹ kan, ti mo si n gba ibẹ lọ sile mi.
"Mo lọ ba ọkan lara ọkunrin meje to n pariwo sira wọn, ọkan fi ọbẹ gun mi lapa, ti ẹjẹ si n tu jade"
“Mo duro ni sọọbu kan lati ra ounjẹ, mo si joko sibẹ pẹlu awọn ọrẹ mi lati jẹun, nibẹ ni ọkan lara awọn ọrẹ mi ti n fi ẹjọ sun mi pe ẹnikan leri si oun.”
Salisu ni oun dide lati lọ ba ọkan lara awọn ọkunrin meje to n pariwo si ara wọn lati mase fa wahala.
“Bi mo ṣe n ba sọrọ, nnkan ti mo ri ni pe o mu ọbẹ jade lati inu asọ, to si gbiyanju lati gun mi sugbọn apa ni ọbẹ naa gun, ti ẹjẹ si bẹrẹ n tu jade.”
Nibẹ ni ija naa pari si, ti ọkunrin to fẹ gun mi lọbẹ si sa kuro nibi isẹlẹ naa sugbọn ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Kano pada tẹ ọkunrin naa lọjọ naa.
"N ko le gba awọn ẹeyan lamọran pe ki wọn mase laja"
"Dokita sọ fun oun pe oun ko le lo apa ike tori bi wọn ṣe ge apa mi to jin"
Salisu ni isẹlẹ naa ti ṣe akoba fun isẹ oun, ti oun ko si ni anfani lati lọ si ibi isẹ mọ .
“Mo kan joko sile ni bayii pẹlu awọn mọlẹbi mi, ti wọn si n tọju mi, fun mi ni gbogbo iwuri ti mo fẹ.”
Lori pe boya yoo ni anfani lati lo apa ike fun isẹ, Salisu ni awọn dokita sọ fun oun pe oun ko le lo apa ike nitori bi wọn ṣe ge apa naa to jin.
“N ko le gba awọn eeyan lamọran pe ki wọn mase la ija.”
Salisu ni pẹlu gbogbo ohun to ti sẹlẹ si oun, oun ko le gba ẹnikẹni lamọran pe ki wọn mase la ija ti wọn ba ri ija.
“Mo gba ohun to sẹlẹ si mi gẹgẹ bii amuwa Ọlọrun ati kadara mii, koda ti n ba ri ibi ti wọn ti ja lọla, ma gbinyanju lati pẹtu si wọn lọkan.
Ileẹjọ ti ran ọkunrin to gun Salisu lẹwọn, to si n gba atẹgun ni ọgba ẹwọn Kuramawa nipinlẹ Kano.