Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mo bẹ̀rẹ̀ òṣèlú, mo sì di Kọmísánà láìròtẹ́lẹ̀ lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún - Wasilat Adegoke

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mo bẹ̀rẹ̀ òṣèlú, mo sì di Kọmísánà láìròtẹ́lẹ̀ lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún - Wasilat Adegoke

Kọmisana fun eto ọdọ ati ere idaraya nipinlẹ Oyo jẹ ọkan lara awọn obinrin ti Gomina ipinlẹ Seyi Makinde yan gẹgẹ bi Kọmisana, to si tun jẹ obinrin akọkọ ti yoo di ipo naa mu.

Ọdun 1994 ni wọn bi Wasilat Adegoke Adefemi si agbole Elegun ni Lanlate, apa Oke Ogun nipinlẹ Oyo.

Nigba to n ba BBC sọrọ, Adegoke salaye pe lati ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni oun ti bẹrẹ si ni darapọ agbo oṣelu.

"Lati igba ti mo ti wa ni ile ẹkọ ni mo nifẹ si oṣelu sise, titi mo fi pari ND ati IT ni mo n se oṣelu.

"Lati ibẹ ni mo ti n lọ si ipade wọọdu awọn oloṣelu.

"Lati ibẹ ni mo ti di ọkan lara awọn igbimọ ipinlẹ to ṣoju ẹkun idibo mi tii ṣe Ila-oorun Ibarapa"

"Gomina sọ pe awọn olori ẹgbẹ lo fa mi kalẹ"

Wasilat Adegoke ni oun iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti Gomina sọ fun oun pe awọn olori ẹgbẹ oṣelu fa oun lati di Kọmisana.

"Nigba ti a dibo tan ni mo ri ipe wi pe Gomina fẹ ri mi, ti inu mi si dun pupọ.

"Nigba ti mo de bẹ, Gomina ni wi pe awọn adari ẹgbẹ l'apapọ ni Ila-oorun Ibarapa ni wọn finufẹdọ, nigba ti awọn ni ki wọn lọ mu eeyan wa fun Kọmisana ni wọn fa kalẹ

"Emi kẹ, mo kọkọ duro, nigba ti mo jade kuro lọdọ Gomina, mo duro wakati kan niwaju geeti wọn, ti mi o ti ẹ mọ ibi ti mo fẹ lọ, mi o mọ ẹni ti mo fẹ pe, sugbọn mo ma fi gbogbo igba dupẹ lọwọ Ọlọrun ati Gomina Seyi Mkinde ati lọwọ gbogbo awọn agbaagba ẹgbẹ ni Ila-oorun Ibarapa."

"Ọpọ obinrin lo fẹ se oṣelu bi temi sugbọn ẹru n ba wọn tori iroyin ofege ti wọn n gbọ nipa oselu"

Adegoke tẹsiwaju pe aimọye obinrin bii tiẹ lo jẹ pe oṣelu wuu lati ṣe sugbọn nnkan ro n gbọ pe o gbudọ fi ẹyin lelẹ jẹ ohun ti mu wọn saa.

"Ko ri bẹẹ, baa ṣe rin la ṣe n ko ni, ohun ni ọrọ ẹda nile aye.

"Ko ma jẹ oṣelu gan an, ko jẹ ibi isẹti eeyan ti n ṣiṣẹ, ipenija maa wa, o ku si ọwọ ẹni ti o ba wa ba, bo ṣe fẹ koju rẹ.

Nnkan ti eeyan ba dẹ ba lọ si ọja ni eeyan maa n gbaju mọ ni ohun ni ọrọ temi.