Ní ìlú Igbeti òkúta iyebíye Marble ya mùrá síbẹ̀, àmọ́ kò so èso sí àpò aráàlú

Ní ìlú Igbeti òkúta iyebíye Marble ya mùrá síbẹ̀, àmọ́ kò so èso sí àpò aráàlú

Ni ilu igbẹti ọkan pataki lara ohun alumọni to le mu owo jade fun aṣuwọn ijọba sodo si ilu yii amọṣa gẹgẹbi ọpọ kaakiri Naijiria, ipenija ti de ba sisọ ọ di orisun.

Nigba ti BBC de ilu Igbẹti lati mọ ibi ti iṣẹ de duro lori wiwa awọn okuta olowo iyebiye to sodo si ilu naa, kọọ naa ṣi lọrọ ri o.

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, Sẹriki ilu Igbẹti, Oloye Emmanuel Adediran ṣalaye pe awọn n fẹ ki ijọba gbe igbesẹ lori ohun alumọni yii ki eyi le mu idagbasoke ba ilu ọhun ati awọn eeyan rẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, Onimọẹrọ Moses Ṣọla Adeyẹmọ ṣalaye pe lara awọn okuta Marble to mọ julọ lagbaye leyi to wa ni ilu Igbẹti ati wi pe ohun to le sọ ọpọ orilẹede di ọlọrọ ni.

Amọṣa o ni gbogbo bi okuta naa ti pọ to ni ilu naa, ijọba ko tii gbe igbesẹ kankan lati sọ ọ di eyi ti yoo mu owo wọ apo araalu ati ijọba.

O ni nibi ti okuta marble yii ṣe iyebiye de, ohun ni wọn fi n ṣeTerazzo, ọda ogun pipo, ohun ẹṣọ ile, ike, taya ọkọ ati bẹẹlọ.