Olùdásílẹ̀ ìjọ Celestial ni bàbá mí, akọrin ìjọ ni mí, kí ń tó padà di oníṣẹ̀ṣe - Olorì Papalanto

Olùdásílẹ̀ ìjọ Celestial ni bàbá mí, akọrin ìjọ ni mí, kí ń tó padà di oníṣẹ̀ṣe - Olorì Papalanto

Yoruba ni ẹni ti ija ko ba, lo maa n pe ara rẹ ni ọkunrin nitori awn iriri aye kan wa, to n gba ẹnu tan.

Bẹẹ ni itan aye Olori Ọba ilu Papalanto nipinlẹ Ogun, Ayaba Bukola Omifunto Jimoh.

Oludasilẹ ijọ Celestial ni baba rẹ, ti oun naa si jẹ akọrin ijọ amọ ti ipenija aye sọ di Yeye Osun to n bọ omi, Sango ati ọpọlọpọ Orisa.

Ọna lati se iwadi nipa igbe aye ayaba naa lo mu ki BBC Yoruba lọ silu Papalanto, ti Olori Jimoh ati ọkọ rẹ, Ọba Razak Jimoh si sọ ohun to se okunfa igbesẹ naa.

“Holy Michael ni Sango, Holy Mary ni Korikoto abiyamọ ọrun”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olori Bukola Omifunto Jimoh ni kii kuku se pe oun dede gba isẹse amọ wn ti sọ fun oun ninu ijọ Celestial pe oun ni ọkọ ọrun.

“Ọkọ ọrun n da mi laamu, ti mo ba si la ala, o maa n sẹ amọ n ko ja kunra.

Osisẹ Nọọsi ni mi, ibi ikore kan ni mo lọ, asiko ti wọn si n ta ọja Bazza ni olusọ ibẹ sọ fun mi pe ki n lọ tẹdo si agbegbe Papalanto, mo si se bẹẹ.”

Olori ni nibẹ ni oun ti pade ọkọ oun lai mọ pe oriade ilu naa ni, oun si ti loyun sinu ki oun to mọ pe ọba alade ni ọkọ oun.

Bakan naa lo s pe awọ́n akọ̀ni igbagbọ̀ bii Holy Michael ni Sango ninu Iṣẹ̀ṣe, ti Holy Mary si jẹ́ Kórìkóto, abiyamọ̀ ọ̀run.

Ọpọ ipenija, to fi mọ isoro ati bimọ ko jẹ ki iyawo mi gbadun aye rẹ, afigba to di Onisẹse – Onipapa

Bakan naa, Onipapa ti Papalanto, Ọba Razak Jimoh, salaye fun BBC Yoruba idi ti aya rẹ fi di Onisẹse lati inu ẹsin Kristiẹni.

Ọba Jimoh ni lootọ ẹsin mẹtalọkan ni awn n se ninu aafin amọ ipenija lo sọ Olori di onisẹse.

“Inu ẹsin Celestial ni mo ti baa, mo si mọ pe o maa yipada nitori pe a ni ipenija to pọ la n koju, paapaa isoro ati bimọ.

Olori mi ko gbadun aye rẹ, emi ti mo jẹ ọkọ rẹ naa ko si gbadun rẹ nigba to n se ẹsin Celestial to n se.

Inu mi dun pe o yipada si isẹse, mo ri iyipada ati irapada lara Olori lati igba to ti di Onisẹse, o si ri idunnu ati ayọ nibẹ.”

“Oyun meje lo bajẹ lara mi, IVF gan kuna, mo saisan doju iku ki Yemoja to ra ẹmi mi pada”

Olori Bukola Omifunto Jimoh tẹsiwaju pe oju oun ri mabo, ki oun to bimọ.

O ni oun le ka oyun meje to bajẹ lara oun ti oun mọ ti awọn dokita ko jade, lai tii ka awọn to bajẹ, to kan mu ẹjẹ lasan jade.

“Oyun meje lo bajẹ, mo se IVF gan, o kuna, pabo lo ja si.

Lọdun 2023, mo se aisan doju iku, wọn ni n ko ni ju isẹju marun lọ mọ, ki n to jade laye.

Ọkọ anti mi lo wa gbe mi lati ile iwosan kan ni ilu Ifo lọ si Cotonou, ti mo si ti lọ lai mọ ohunkohun to n sẹlẹ si mi mọ.”

“Orisa lo pe mi, Orisa ni ọkọ mi, n ko ni ọga, Olodumare nikan ni ọga mi.”

Olori tẹsiwaju pe awọn onisẹse to wa ni Cotonou ni ki wọn fi omi okun wọn mi lara, ki n maa baa ku, ki n to ọdọ awọn.

Nigba ti a de Cotonou, aworan Yemoja ti mo wo, ni Yemoja ti jade si mi, o ba mi sọrọ, mo si n se awọn ohun to ni ki n maa se laimọ.

Mo kọ orin Osun bii ogoji bi o tilẹjẹ pe orin Celestial nikan ni mo mọ tẹlẹ loju aye.

Iyatọ ti ba aye mi lati igba ti mo ti n bọ gbogbo Orisa, kii se Osun nikan.

Orisa lo pe mi, Orisa ni ọkọ mi, n ko ni ọga, Olodumare nikan ni ọga mi.”