Ìlú Johannesburg rèé tó ń di ahoro, bí ọ̀pọ̀ jàǹdùkú ṣe ń fipá gba ilé láti jalè, lo òògùn olóró

Ìlú Johannesburg rèé tó ń di ahoro, bí ọ̀pọ̀ jàǹdùkú ṣe ń fipá gba ilé láti jalè, lo òògùn olóró

Ilu Johannesburg ni orilẹede South Afrika ni ipade apapọ awọn asaaju orilẹede to wa labẹ aburada G20 yoo ti maa waye lọdun yii.

Igba akọkọ ree ti wọn yoo gbe ipade apero naa wa si ẹkun Afirika, ọjọ kejilelogun si ikẹtalelogun osu kọkanla yii si ni ipade naa yoo maa waye.

Sugbọn bi ọpọ orilẹede ni awujọ agbaye se n foju sọna fun ipade apero naa, ẹka ọtẹlẹmuyẹ BBC tan ina iwadi rẹ si aarin ilu naa lati mọ bo se ri.

Sugbọn iwadi wa fihan pe ilu naa n daru lọwọ, to si le lulẹ nigbakuugba.

Idi ni pe awọn ilegbe lọpọ yanturu to le ni ọgọrun ni awọn eeyan kọ silẹ, ti wọn ko gbe mọ, tawọn ile naa si ti dẹnukọlẹ.

Ibeere ta wa n beere ni pe ki lo fa isẹlẹ yii?

Ikọ BBC Africa Eye ri awọn igbọnsẹ to ti san lọ si isalẹ ile kan, eyi to fẹ bo awọn ọkọ inu ile naa mọlẹ

Akọroyin kan ni ẹka ọtẹlẹmuyẹ BBC Africa Eye, Ayanda Charlie lasiko to n lọ yika awọn adugbo ti ọrọ kan, bawọn eeyan sọrọ ninu iwadii rẹ.

Nigba to n beere pe se ko si omi lati lo tabi se ọpa omi ko sisẹ ni, idahun tawọn eeyan naa fun ni pe ti wọn ba da omi, se lo maa n lọ silẹ.

Koda, ikọ BBC Africa Eye ri awọn igbọnsẹ to ti san lọ si isalẹ ile kan eyi to fẹ bo awọn ọkọ inu ile naa mọlẹ.

Koda, ẹnikan to ba BBC sọrọ ni "ọpọ awọn ile to wa nilu Johanesburg ni awọn janduku ti ja gba, wọn a lọ jale, ti wọn si maa n gba inu yara wọle, bẹẹ ni wọn n sa pamọ sawọn aja ile naa."

"Owo lo jẹ awọn ọlọpaa logun, ti o ba ti lowo nla lati gbe kalẹ, ọrọ ti buse amọ ọlọpaa ti ko ba gba owo, yoo fi iku se ifa jẹ"

Ẹlomiran to ba BBC sọrọ lori isẹlẹ yii wa lara awọn eeyan to n sọ ọpọ ile di ahoro tẹlẹ amọ to ti jawọ ninu iwa laabi naa.

"Okoowo tita oogun oloro ni wọn n se julọ ninu awọn ile alopati yii, ọpọ awọn ile si ni wọn ti ja gba fun isẹ naa.

Fun awọn ọlọpa, owo lo jẹ wọn logun, ti o ba ti lowo nla lati gbe kalẹ, ọrọ ti buse amọ ọlọpaa ti ko ba gba owo, yoo fi iku se ifa jẹ."

Nigba ti wn n bi pe bawo lo se ri lara rẹ lati fipa gba awọn ile lọwọ onile, ti ile se di alopati batii, ọkunrin naa ni oun tuuba fun iwa buruku ti oun ti hu sẹyin naa.

Ileesẹ ọlọpaa ni Johannesburg kọ lati sọrọ, awọn alasẹ ilu naa seleri lati tubọ mura si isẹ wọn

BBC Africa Eye tun kan si awọn alasẹ ilu Johanesburg, ti wọn si salaye pe isẹlẹ bawọn janduku se n ja ile gba, sọ ile di alopati ko jẹ tuntun si awọn.

Amọ wọn seleri lati tubọ mura si isẹ lati mu adinku ba iwa yii.

Nigba ti BBC kan si ileesẹ ọlọpaa nilu Johanesburg, wọn kọ lati sọrọ lori iwadi naa, eyi to nii se lori ẹsun ti wọn fi kan awọn ọlọpaa pe wọn n gba riba lọwọ awọn janduku naa.

Ati ẹsun to ni se pe awọn janduku n da ijaya silẹ laarin ilu, ti wọn si n lọwọ ninu iwa ipaniyan amọ a ko ri idahun kankan lori awọn ẹsun naa lọdọ ileesẹ ọlọpaa ọhun