Wo orílẹ́-èdè mẹ́fà tí wọ́n ní iye àwọn tó ni ààrùn HIV jùlọ lágbàáyé

Aworan apejuwe HIV

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pẹlu bi aarun HIV ṣe n lọ silẹ, aarun kokoro aṣekupani naa ti ran ọpọ eeyan lọ sọrun aremabọ, bẹẹ si ni ajọ iṣọkan agbaye, UN ti wọn n ṣiṣẹ lati gbogun ti arun HIV/AIDS ti ṣe ikilọ pe gbogbo agbaye ko ṣetan lati gbogun ti ijamba ti kokoro arun naa n ṣe.

Ajọ UNAIDS jẹ ko di mimọ pe awọn eeyan to din diẹ ni ogoji miliọnu, 39.9m, ni wọn n gbe pẹlu kokoro arun naa lagbaye, ati pe awọn to to ida meji iye yii lo jẹ apa guusu ati ila-oorun ilẹ Afrika ni wọn ti wa.

Iye awọn to ni aarun yii ti dinku ni ida mọkandinlogoji lati ọdun 2010 titi di asiko yii, ati pe iye awọn to n ku nipasẹ rẹ ti dinku si idaji.

Ṣugbọn ṣa, awọn orileede bii Afghanistan, Egypt, Fiji, Philippines, Papua, New Guinea ati Saudi Arabia ni wọn ti ṣakọsilẹ alekun ida ọgọgun awọn to lugbadi aarun yii laarin ọdun 2010 ati 2023.

Awọn orileede to wa ni Sub-Saharan ni wọn ti gbogun ti HIV yii gidi

Awọn orileede ti wọn ni ida marundinlọgọrin (75%) nipa didẹkun arun HIV tuntun yii

Àtẹ akọsilẹ ajọ UNAIDS

Oríṣun àwòrán, UNAIDS 2024

Àkọlé àwòrán, Aworan akọsilẹ ajọ UNAIDS

Kenya, Malawi ati Zimbabwe, to fi mọ Nepal ni wọn ti gbiyanju lati mu adinku ba iye awọn to n lugbadi kokoro aarun naa ni ida marundinlọgọrin (75%) lati ọdun 2010.

Ilẹ Afrika ti wa n lewaju nipa igbiyanju lati gbogun ti arun AIDS.

Awọn orileede mejidinlogun ti mu adinku ba iye arun naa ti wọn n ṣakọsilẹ rẹ lọdọọdun pẹlu ida ọgọta (60%) lati ọdun 2010.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọpọ ninu wọn lo wa ni ẹkun ilẹ Afrika, to fi mọ awọn orileede bii Lesotho, Eswatini, Benin, Ethiopia, Rwanda, Botswana, Eritrea, Liberia, Burkina Faso, Togo, Zambia, Burundi, Guinea-Bissau ati Uganda, ati pẹlu Tajikistan, Portugal, Belarus, to fi mọ Italy.

Lara awọn to ti lugbadi arun yii, ida mẹtadinlọgọrin (77%) ni wọn n gba itọju ti a mọ si ‘antiretroviral therapy’. Lawọn orileede to wa ni ẹkun ilẹ Afrika ti sub-Saharan, ida mejilelọgọrin (82%) awọn eeyan ni wọn n gba iru itọju bayii.

Bakan naa, o ti foju han pe iye awọn to ti lugbadi aarun yii ti ni ireti nla lati gbe ile aye ti le ni ọdun marun-un, lati ẹrindinlọgọta lọdun 2010 si okanlelọgọta lọdun 2023, nitori aṣeyọri ti wọn ti ṣe nipa gbigbogun ti arun naa.

Ajọ UNAIDS sọ pe gbigbogun ti arun naa lawọn ilẹ Afrika ti fun awọn eeyan to ni arun HIV ni anfaani lati mu ẹdinku ba itankalẹ rẹ ni gbogbo igba.

Awọn ofin to lodi si ibalopọ ọkunrin si ọkunrin ati obinrin si obinrin – to wọpọ lawọn orileede kan – maa n daabo bo awọn to wa ninu ewu lati lugbadi rẹ.

Idagbasoke ni awọn ẹkun sub-Saharan nilẹ Afrika

“Awọn aṣeyọri ti wọn ti ṣe ninu igbesẹ lati gbogun ti arun yii, paapaa julọ lawọn ẹkun sub-Saharan ilẹ Afrika, ti ṣafihan ipa ti ifọwọsowọpọ awọn adari ati igbiyanju awọn orileede lagbaye le ni ninu gbigbogun ti arun naa,” igbakeji alakoso ajọ UNAIDS, Christine Stegling lo sọ eyi.

Ninu idahun atẹjiṣẹ to fi ranṣẹ si BBC, o sọ pe o ṣe pataki fun awọn adari lati dojukọ ọna idagbasoke lati daabo bo ara wọn lọwọ arun naa, ki wọn si yọ awọn iṣoro to le dena awọn eeyan lati maa lọ sile iwosan kuro.

“Agbaye ti wa loju ọna lati tẹri arun AIDS ba gẹgẹ bi ailera to n dunkooko, nitori pe aini anfaani ti awọn ohun eto ilera to koju oṣuwọn gan an ni iṣoro nla to n koju awọn eeyan, paapaa julọ awọn agbegbe ti wọn ya sọtọ. Aabo to lodi si HIV gan-an jẹ ipenija nla.”

Aworan enikan to n gba itoju nile iwosan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣugbọn ṣa, gbigbogun ti arun yii lawọn orileede kan kere jọjọ.

Awọn orileede bii Papua New Guinea, Afghanistan, Fiji, Philippines, Egypt ati Saudi Arabia ni wọn n ṣakọsilẹ alekun ida ọgọrun awọn to n lugbadi arun AIDS laarin ọdun 2010 ati 2023.

Bi a ba wo iye awọn to n gbe lawọn orileede wọnyi, ko si eeyan to pọ ti wọn n gbe pẹlu arun HIV ni Afghanistan, Egypt ati Saudi Arabia.

Ṣugbọn ireti wa. Akọsilẹ UNAIDS ṣafihan wi pe bi wọn ba ṣi n ko owo silẹ lati gbogun ti arun yii, arun HIV le parun kaakiri agbaye laarin ọdun mẹfa si asiko yii.