You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun ti gómìnà Akeredolu sọ nípa ìkọlù tuntun tó wáyé nílùú Owo
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti ni ki awọn eeyan ilu owo lọ fi ọkan wọn balẹ lẹyin ikọlu to waye niluu naa lọjọru.
O ni awọn agbebọn to kọlu ileeṣẹ Craneburg Construction Company, niluu Owo ko wa lati wa pa ẹnikẹni, bi ko ṣe lati ba awọn irinsẹ ileesẹ naa kan jẹ.
Akeredolu lo sọ ọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si ileesẹ naa, toun tawọn olori awọn ileeṣẹ eto abo ipinlẹ ọhun.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ Akeredolu, Richard Olatunde, fi lede, o ni “Mo wa lati fi ọkan awọn eeyan balẹ ni.”
“Dajudaju, ohun to ṣẹlẹ nibi kii ṣe gibiyanju lati ji eeyann gbe lọ, nitori wọn ko ji ẹnikẹni gbe, bẹẹ ọpọ eeyan lo si n gbe nibi.”
“Lootọ ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lẹgbẹ ogiri ṣugbọn wọn ko wọ inu ile lati pa ẹnikẹni, awọn to n ṣọ ẹnu ọna ileeṣẹ naa lawọn meji pere ti ibọn ba.”
Ni ṣe ni wọn wa ba dukia ileeṣẹ yii jẹ, wọn ko wa pa ẹnikẹni
Aketi tẹsiwaju pe “Nitori naa, o han gbangba si wa pe wọn mọọmọ wa ba awọn dukia ileeṣẹ yii jẹ ni.”
“Awọn ọkọ to wa nibi to aadọta amọ a ṣi n ṣagbeyẹwo wọn na, a ko tii le sọ ni pato eredi ti wọn fi ṣakọlu ṣubọn ki ṣe ohun to yẹ ko da ipaya sọkan awọn eeyan wa.”
Akeredolu tun fi ọkan awọ oṣiṣẹ ileesẹ naa balẹ pe ilu Owo jẹ ilu ti abo yoo ti wa lori wọn, ki wọn ma si bẹru lati ṣiṣẹ nibẹ.
O ni o ṣeeṣe ki ijọba ṣe iranlọwọ fun ileeṣẹ naa pẹlu awọn ẹṣọ alabo to ni ohun ija ogun lọwọ.
Lẹyhin naa lo rọ awọn eeyan ilu Owo ki wọn fi ọkan wọn balẹ, ki wọn si maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai si ifoya kankan.