You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Joy Omoyeni, akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó gba A1 mẹ́sàn án
Ki ni orukọ ti ẹ maa n pe awọn ọmọ to ba mọwe gidi ni ile ẹkọ lọdọ tiyin.
Orukọ naa ni ki ẹ fi ṣe akawe ọmọdebinrin yii - Ọmọyẹni Joy.
Ọmọyẹni Joy jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Telnet Internation Schools ni ilu Akurẹ.
Ninu idanwo aṣekagba girama to joko fun, gbogbo ẹkọ mẹsan to joko ṣe idanwo rẹ ni o ti yege pẹlu ami A1.
Ijọba ipinlẹ Ondo ti kan sara si ọmọdebinrin yii ti wọn si ti tọka sii gẹgẹbii ara awọn ogo ati awokọṣe fun awọn ọmọobinrin lorilẹede Naijiria.
Nitori pe o fẹ gbọ ede Yoruba lo fi ni ka gbe oun wa si ilẹ Yoruba wa pari ẹkọ rẹ - Baba Joy Ọmọyẹni
Awọn obi rẹ ṣalaye pe nitori ki o le gbọ ede Yoruba ni wọn ṣe gbe wa si ilu Akurẹ lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ.
Ọgbẹni Victor Ọmọyẹni to jẹ Baba rẹ ni ara nnkan to n jẹ ipenija fun oun ni aigbọ ede ede Yoruba rẹ.
O ni ọpọlọpọ igba ni ọmọdebinrin naa maa n sọ fun oun pe oun fẹ kọ nipa ede ibinibi oun. Eyi lo si mu ki oun pinnu lati gbe e wa si ilu Akurẹ