You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Òfin tí ìjọba Nàìjíríà fi de ọtí inú ọ̀rá, Pẹlẹbẹ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tó gbẹ̀yìn lọ́dún 2025, ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí
Ijọba apapọ Naijiria fofin de ṣiṣe , tita, tabi mimu ọti inu ọra ti ọpọ mọ si pẹlẹbẹ atawọn orukọ miran.
Gẹgẹbi aṣẹ ti ijọba apapọ pa lẹyin ti ile aṣofin apapọ fẹnuko lori ọti inu ọra naa, aṣẹ naa fẹsẹ mulẹ bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kejila ọdun 2025.
Ile igbimọ aṣofin lo paṣẹ fun ajọ to n ri si amọjuto elo oogun, ounjẹ ati ohun mimu ni Naijiria, NAFDAC, atawọn ajọ mii lati ri daju pe ẹnikẹni ko ta ọti inu ọra ni Naijiria mọ bẹrẹ lati inu oṣu Kejila ọdun 2025 yii.
Awọn aṣofin naa tun fẹnuko pe wọn ko ni fun awọn to n ta ọta ni aye mii lẹyin aṣẹ ti wọn pa yii.
Iwọnyin lawọn igba ti ijọba ti gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria
Lootọ kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba Naijiria yoo maa pa iru aṣẹ bayii.
- Oṣu kejila ọdun 2018 - Ọdun naa ni igba akọkọ ti ijọba atawọn oniruru ajọ buwọlu adehun latin fopin si pipo ọti ninu ọra, paapaa awọn ọti ti iwọn rẹ ko ju 200ml.
- Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024 – NAFDAC bẹrẹ si n ko awọn ọti naa lori igba lati le mu aṣẹ iwe adehun naa ṣe.
- Oṣu keji si oṣu Kẹfa ọdun 2024 – Ile igbimọ aṣofin da si ọrọ naa wọn si rọ NAFDAC lati dawọ kiko rẹ kuro lori igba duro latari awọn ti yoo padanu owo ati iṣẹ wọn, paapaa ipa ti igbesẹ naa yoo ni lori ọrọ aje araalu to n ta a.
- Oṣu Karun un, ọdun 2024 – NAFDAC gbẹsẹ kuro lori aṣẹ naa fun igba diẹ titi di ipari ọdun 2025 ki wọn le ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn ti rọrọ naa kan.
- Oṣu Kọkanla, ọdun 2025 – ile igbimọ aṣofin kan an nipa fun NAFDAC ko bẹrẹ aṣẹ naa ko si gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria lai fun awọn to n po o atawọn to n ta a n afikun gbendeke mii mọ.