You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé alágbẹ̀dẹ kò gbọdọ̀ jẹ ejò? Ogunsina ṣàlàyé ìdí abájọ
Ogun kọrọbiti kọrọbiti, Ogun kọrọbiti kọrọbiti, ogun n bẹ nile, ogun n bẹ loko.
Ogun n bẹ ni ibode to fi aja rọri, ki Ọlọrun ma jẹ ki a rija rẹ.
Bayii ni alagbẹdẹ Ogunsina Afuye to fi ilu Abeoku ṣe ibugbe ṣe ki Ogun to niiṣe pẹlu iṣẹ adayeba to n ṣe.
Ogunsina ni ‘’lati kekere ni wọn ti fi mi sidi iṣẹ alagbẹdẹ, ki n ṣe pe boya mo kọ ọ, eeyan o kii kọ iṣẹ alagbẹdẹ.
Wọn ko n kọ iṣẹ alagbẹdẹ tori wọn ko ni pada wa ti wọn ba ti ni ijamba diẹ, awọn ti wọn ba bi sidi rẹ lo maa n saba ṣe iṣẹ naa.
Baba mi bi wa sibi iṣẹ naa ni, emi naa si ti n fi le awọn ọmọ temi naa lọwọ.''
Ogunsina sọ pe ''ko si ohun ti a ki n ṣe nibi, bii ka rọ osu, agogo, aja, akeede, ẹrinle, aake ẹran, at i bẹẹ bẹẹ lọ.
Agbẹdeẹ bambam, agbẹdẹ abalaye leleyii, o yatọ si ti ‘’Goldsmith.’’
Irin dudu bi awọn irinlẹ, osu, agogo lawa maa n ṣe nibi.
Eewọ to wa nidi iṣẹ yii ni pe alagbẹdẹ ki i jẹ ejo, ko dẹ gbọdọ jẹ irẹ.
Ti o ba jẹ awọn nkan yii, o maa ba irinṣẹ wa jẹ.
Nibi gbọgbọ lawọn eeyan ti maa n wa bọ Ogun lagbẹdẹ wa nibi, kaakiri Naijiria ati niluu oyinbo ti adura wọn si n gba.''