Wo ohun tí Ààrẹ Tinubu sọ níbi ìpàdé Arab Islamic nílùú Saudi Arabia?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aarẹ Bola Tinubu ti pe fun idaduro ogun ni Gaza, to si ṣekilọ pe rogbodiyan to n lọ lọwọ ni Palestine ti pẹ ju, to si n fa ọpọ inira.

Tinubu sọ eyi lasiko to n sọrọ nibi ipade Arab-Islamic lori awọn iṣẹlẹ to n waye ni agbegbe Middle East, Aarẹ Tinubu kọminu lori ipo ti awọn eeyan agbegbe naa wa bayii.

Ipade ọlọjọ kan yii ni ọpọ awọn olori kaakiri agbaye wa ni ijoko.

Aarẹ Tinubu ni ojutu si ohun to n ṣẹlẹ Gaza ni ki orilẹede Israel ati Palestine pinnu lati gbe papọ , ki wọn si da bobo ara wọn.

“Ogun to lọ ni Palestine ti pẹ ju, to n fa ọpọ inira fun awọn eeyan to wa ni agbegbe na.

“Gẹgẹ bii aṣoju orilẹede to bọwọ fun idajọ dodo, to si bọwọ fun ẹmi awọn eeyan, a n pe fun ti opin de ba ogun yii.

“Gbogbo agbaye ni lati wa ọna si opin ki ogun to n pa ọpọ eeyan ni Gaza, o ti n pẹ ju.

“Ko si oṣelu kankan to yẹ ko wa saaju ẹmi awọn araalu.”

Bakan naa ni Aarẹ pe fun ẹgbẹ ti ọrọ kan pe ki wọn bọwọ fun ẹtọ awọn araalu.

“Gẹgẹ ofin agbaye se sọ, awọn orilẹede ni lati da bobo ara wọn sugbọn dida bobo ara ẹni naa ni gbedeke, to si ni ọna ti o yẹ ki wọn gbe gba.”

O fikun pe awọn eeyan Gaza ko gbọdọ jẹ ki ala wọn, ẹmi wọn ati ọjọ ọla wọn bajẹ lonii.

Tinubu tun kan si awọn olori orilẹede mejeeji pe ki wọn alaafia laaye , ki wọn si gba onikaluku laaye lati kọ orilẹede rẹ, ti opin si de ba ogun.

“Lati le jẹ ki eyi wa si imusẹ, o yẹ ki ijiroro waye, ki wọn si bọwọ fun itan wọn. Gbogbo wa lamọ pe ogun naa ko bẹrẹ ni ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023 sugbọn opin ogun yii ni gbogbo wa a jọ ri pe o wa si imusẹ.

Aarẹ Tinubu kan sara si Ọmọọba Saudi fun bi o ṣe gbe ipade naa kalẹ, ryi to ni o pese anfani lati jẹ alaafia jọba lagbaye.

Ikọlu Hamas si orilẹede Israel lo waye ni ọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023, nibi ti ọpọ eeyan ti padanu ẹmi wọn.

Lati igba naa ni orilẹede Israel ti fẹ gba Gaza, ti wọn si ti ṣekupa eeyan 43,000, ti ọpọ awọn oloogbe yii jẹ obinrin ati ọmọde.

Orilẹede Israel pinnu pe awọn ko ni jawọ ninu ogun titi awọn yoo fi rẹyin ikọ ologun Hamas.

Kí ni èrèdí ìpàdé Arab Islamic tí Ààrẹ Tinubu lọ?

Aarẹ Bola Tinubu ti gbera kuro lorilẹede Naijiria lati lọ fun ipade Joint Arab-Islamic lorilẹede Saudi Arabia.

Awọn olori orilẹede to lọ fun ipade naa ti wa ni Riyadh, to jẹ olu ilu Saudi Arabia, nibi ti ipade ẹlẹkeji iru rẹ yoo ti waye lọjọ Aje, ọjọ kọkanla ọdun 2024.

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu pẹlu awọn olori orilẹede mii lo ti wa ni orilẹede Saudi Arabia nibi ti ipade naa yo ti waye.

Ipade naa lo da lori wiwa ojutu si awọn iṣoro to n gba agbegbe Arabu laamu lagbaye.

Gẹgẹ bii atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga gbe sita, Ipade naa ni Oba Salman ati Ọmọọba Mohammed bin Salman gbe kalẹ

Ọdun to kọja ni ijoko apero naa bẹrẹ nibi ti wọn sọrọ lori ogun Gaza ati awọn iṣoro mii to n da agbegbe naa laamu.

Gẹgẹ bii ohun ti agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga se sita, o ni aarẹ Bola Tinubu yoo sọrọ nipa ogun Israel-Palestine.

O ni Aarẹ yoo sọrọ nipa ipe orilẹede Naijiria, eyi to n pe fun idawọ duro ogun, ki wọn si yanju ọrọ naa ni tubinubi.

Awọn osisẹ ijọba to tẹle Aarẹ ni Amabassador Yusuf Tuggar, Mallam Nuhu Ribadu, Alhaji Mohammed Idris ati Mohammed Mohammed.

Kete ti ipade ba pari ni Aarẹ Bola Tinubu yoo pada si orilẹede Naijiria