Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

A di gbere, a darinako, o tun di bẹni ba n jọni

Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Olakulehin ti darapọ mọ awọn babanla rẹ

Ni owurọ oni ni Ọba Olakulẹhin re iwalẹ aṣa lẹyin ọdun kan lori apere

Ọjọ Karun-un, oṣu Keje yii ni Ọba Olakulẹyin ṣayẹyẹ ọjọ ibi aadọrun-un loke eepẹ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ẹyin eeyan ẹ fura o

Eyi ni ikilọ awọn ọlọpaa lori ajọdun awọn ẹlẹgbẹ okunkun to n waye lonii

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oniruuru iwa ibi lo le tọwọ awọn eeyan naa waye

Ti wọn si la awọn ilana kan kalẹ lati moribọ lọwọ wọn

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ile Naijiria, NLC ti dunkoko lati gunle iyanṣẹlodi

Ṣe wọn tun n fẹ alekun owo oṣu ni

Rara o, ẹgbẹ oṣiṣẹ ni gbogbo kudiẹkudiẹ to n waye ni Naijiria bii ọwọgogo ounjẹ, aisi eto aabo lo fa a

Alaga NLC ni ipinlẹ Ogun sọ fun BBC Yoruba pe lati igba pipẹ lawọn ti ba ijọba jiroro lori awọn iṣoro yii

Ọjọ wo ni wọn fẹ bẹrẹ iyanṣelodi naa?

Fun ẹkunrẹrẹ

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́