You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ni Ààrẹ Tinubu fẹ́ fi ₦7trn tó fẹ́ gba ìyọ̀ǹda ilé aṣòfin àgbà láti yá ṣe?
Aarẹ Bola Tinubu ti kọwe ranṣẹ si ile aṣofin agba lati gba iyọnda lati lee ya owo to din diẹ ni biliọnu mẹsan dollar ati ọgọrun miliọnu euro lati ṣe awọn iṣẹ akanṣe jakejado Naijiria.
Owo yii, ti wọn ba ṣẹ ẹ si naira, yoo le nkan bii igba biliọnu ni tiriliọnu meje naira.
Ibeere aarẹ yii jẹyọ ninu iwe ti aarẹ ile aṣofin ọhun, Sẹnetọ Godswill Akpabio, ka niwaju ile naa lọjọ iṣẹgun leyi to ti wipe owo ti Tinubu n beere fun naa jẹ lara akọsilẹ owo ti ijọba apapọ fẹẹ ya laarin 2022 si 2024 leyi ti aarẹ Muhammadu Buhari fọwọ si ko too kuro lori aleefa.
O wi pe awọn iṣẹ akanṣe ọhun to wa kaakiri awọn ẹlẹkanjẹka ọrọ aje ni wọn ṣa lẹyin ayẹwo ipa ti wọn yoo ko lori ọrọ aje ati anfani ti yoo ṣe fun idagbasoke orilẹ-ede.
Ki lo wa ninu lẹta ọhun gan?
Lara ohun to wa ninu lẹta naa ka pe: “mo fẹẹ ki ile aṣofin yi kiyesii pe ijọba to kọja buwọ lu ilana ẹyawo laarin ọdun 2022 si 2024 ninu ipade igbimọ iṣejọba to waye lọjọ kẹẹdogun oṣu karun, ọdun 2023.
“Awọn iṣẹ akanṣe ọhun la wa kaakiri gbogbo ẹka ọrọ aje pẹlu itempẹlẹ mọ awọn ohun amayedẹrun, iṣẹ ọgbin, eto ilera, ipese omi, ọna, eto abo, ipese iṣẹ ati iṣatunto eto inawo.
“Fun idi eyi, oye ti a fẹẹ ya jẹ biliọnu mẹjọ o le ọkandilẹẹdẹgbẹrin miliọnu (ati ẹsun diẹ) dollar ati ọgọrun miliọnu euro.”
Ẹwẹ, Aarẹ Tinubu ni yoo gbe aba eto iṣuna ọdun 2024 kalẹ niwaju apapọ ile igbimọ aṣofin lonii.