You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo lo ọjọ́ mẹ́ta ní àhámọ́ àwọn ajínigbé, ojú mi rí tó
Akọ̀ròyìn kan ní ìpínlẹ̀ Ogun ti kó tó sì rò lórí àwọn nǹkan tí ojú rẹ̀ rí nígbà tó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.
Oluseun Oduneye ló jẹ́ olóòtú The Issues Magazine tí àwọn ajínigbé kan lọ jí gbé lásìkò tó ń kúrò níbi tó ti lọ ra nǹkan tí wọ́n fẹ́ jẹ nílé.
Ó ní bí òun ṣe ń kúrò níbi tí òun ti fẹ́ ra dòdò àti ẹ̀wà tí ìyàwó òun ní kí òun rà bọ̀ ní àwọn ajínigbé náà yọ sí òun nídìí ọkọ̀ òun.
“Wọ́n yọ ìbọn sí mi, mo ti ẹ̀ lérò pé mọ́tò tàbí fóònù ni wọ́n fẹ́ gbà lọ́wọ́ mi ni àmọ́ wọ́n ní àwọn kò bámi ṣeré tí wọ́n sì fún mi lọ́rùn.”
“Wọ́n sọ mí sí ẹ̀yìn ọkọ̀ tí wọ́n sì fi okùn di ọwọ́ pé Kano ni àwọn ń gbé mi lọ.”
Oduneye ní àwọn ajínigbé náà gbé òun lọ sínú igbó kìjikìji tí a sì lo ọjọ́ mẹ́ta nínú igbó tí wọ́n fi mí pamọ́ sí.
Ó ní wọn kò fún òun ní oúnjẹ tàbí omi láti mú, kódà òun tún bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n gba òun láàyè láti tọ̀ kí òun mu ìtọ̀ òun àmọ́ àwọn ajínigbé náà fárígá.
“Nígbà tó yá ni wọ́n ń bèèrè owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ mi, wọ́n ní àwọn máa gba ogún mílíọ̀nù náírà.”
“Ìyàwọ mi ti ń sáré láti wá owó náà kí àwọn ọlọ́pàá tó gbàmí sílẹ̀ ní bùbá àwọn ajínigbé yìí.”
Mo ni nǹkan tó máa ń ṣe atọ́nà ibi tí ọkọ̀ mi bá wà
Oduneye ṣàlàyé pé lásìkò tí ìyàwó òun ń wá owó ìtúsílẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ òun.
Ó fi kun pé ẹ̀rọ tí wọ́n fi máa ń ṣe àwárí nǹkan ìyẹn “tracker” tó wà lára ọkọ̀ òun ló okùnfà bí àwọn ọlọ́pàá ṣe rí ọkọ̀ òun ní Idimu ní ìpínlẹ̀ Eko.
Ó ní èyí lọ jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá yawọ ibi tí àwọn ajínigbé náà gbé ọkọ̀ sí, tí ẹni tó wà nínú igbó pẹ̀lú òun kò ríbi bá àwọn yòókù rẹ̀ sọ̀rọ̀ mọ́.
“Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe wá sí ibi tí wọ́n fi mí sí nínú igbó nìyí tí mo sì gba ìtúsílẹ̀.”