Ìlù gángan ni a fi ń ṣe iṣẹ́ ìhìnrere àṣà Yoruba f'àwón ọmọde- Adebayo Ayodeji

Ìlù gángan ni a fi ń ṣe iṣẹ́ ìhìnrere àṣà Yoruba f'àwón ọmọde- Adebayo Ayodeji

Adebayo Ayodeji, to n kọ awọn ọmọde ni ilu gangan ti ṣalaye pe ilu naa ni oun fi n ṣe iṣẹ iyinrere aṣa Yoruba.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Ayodeji sọ pe pupọ ninu awọn ọmọde naa, ti wọn jẹ ọmọ ilẹ okeere alawọ dudu ni ko tii ri irufẹ awọn ilu bẹẹ ri.

Ayodeji ni eto ikọnilorin kan, eyii to maa n ṣe lẹẹmeji laarin oṣi niluu Eko, nibi to ti n kọ awọn ọmọde nipa pataki ilu ninu aṣa adulawọ.

O ni eredi ti oun fi n ṣe idanilẹkọọ naa ni lati jẹ ki awọn ọjẹ wẹwẹ mọ sii nipa aṣa ilẹ Yoruba.

Ọkan ninu awọn ọmọde to wa nibi ikẹkọọ naa, Adesola Dauda-Talabi sọ fun BBC pe inu oun dun lati jẹ ọkan lara awọn to n kọ bi wọn ṣe n lu ilu Yoruba ọhun.