Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Wo o mo ti digba dagbọn mi tan bayii, ilẹ okeere ya

Ẹhn ẹhn, iṣẹ ki lo fẹ maa ṣe ti o ba de ibi ti o n lọ?

Emi ma ti yanju ara mi, mo ti sanwo fun ẹnikan nilẹ okeere lati bami waṣẹ silẹ

Ah, o jẹ rọra, ko ma lọ ko sọwọ awọn onijibiti

Ṣe wọn maa n lu gbajuẹ nilẹ òkèère ni?

Ṣe o o ti ka iroyin ti BBC ṣẹṣẹ gbe jade nipa awọn to n lu awọn ọmọ Naijiria ni jibiti lati fun wọn niṣẹ ni UK?

Irọ ni o, nibo lo wa?

Kan soju opo bbc.com/yoruba lati ka a lẹkunrẹrẹ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ṣe o tun ti gbọ?

Pe kini?

Pe o ṣeeṣe ki o sun ẹwọn tabi san faini ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira to ba kọ lati dibo

Nigba wo niyẹn bẹrẹ?

Ile aṣofin Naijiria n po aba naa pọ lọwọ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Owo oṣu mẹrin ni mo n jẹ awọn oṣiṣẹ nibi ti ilu le de

Eyi ni ọrọ to jade lẹnu gbajumọ oṣere tiata, Ibrahim Chatta

O ni awọn olori Naijiria nilo lati ṣe dada faraalu nitori ilu o fararọ

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́