Wo tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tó ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ Guiness World Records ní ìgbà 13 fún bọ́ọ̀lù gbígbá

Wo tẹ̀gbọ́n-tàbúrò tó ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ Guiness World Records ní ìgbà 13 fún bọ́ọ̀lù gbígbá

Yoruba sọ pe ohun ti a ba mọ ọ ṣe, bi idan lo ma n ri.

Bẹẹ gan an ni ọrọ ri fun tẹgbọn-taburo, Confidence ati Victor Kipo to jẹ pe ko si ibi ti wọn ko le fi gba bọọlu ninu ẹya ara wọn.

Ami ẹyẹ Guiness World Record mejila ni awọn ọmọde naa ti gba lapapọ fun bi wọn ṣe le fi bọọlu ṣere ọwọ.

Ọmọ ọdun mẹsan-an ni eyi aburo, igba mẹta lo ti gba ami ẹyẹ yii. Oun si ni ọjọ ori rẹ kere julọ ninu awọn to ti gba ami ẹyẹ GWR ni Naijiria.

Victor sọ pe ọpọ eeyan ma n sọ pe idan ni awọn n pa.

Bakan naa lo ni oun ti la awọn ipenija bii ipalara ati ebi kọja.

O ni ṣugbọn gbogbo irora naa ti di ayọ.

“Iya mi lo ṣe iwuri fun mi nidi nnkan ti mo n ṣe.”

Olukọni wọn, Chukwuebuka Ezugha sọ pe itara nla ni Victor ati Condidence ni fun ere bọọlu.

O ni nnkan to wu n ni lati gba bọọlu ni awọn ibi nla.