Àwọn olóṣèlú Krìstẹ́nì yarí lórí bí ìjọba ṣe fẹ́ fi òfin de ọtí mímu

Awọn oloṣelu Kristẹni ti ni igbesẹ ile igbimọ aṣofin orilẹede Iraq to fi ofin kiko ọti wọle ati ti ta ọti ni ko bojumo rara, ti wọn si ti bẹrẹ igbiyanju lati yi ofin naa pada.

Lọjọ Satide ni awọn igbimọ naa ni ki awọn agbofinro bẹrẹ si ni rii pe ofin ọhun di mimu ṣẹ. Oṣu to kọja ti wọn buwọlu ofin naa lẹyin ti ọpọlọpọ awuyewuye waye.

Awọn oloselu naa jẹ marun un ni ile igbimọ aṣofin ni wọn si ti gbe ọrọ naa lọ ileẹjọ pe o lodi si ijọba awaarawa.

Mimu ọti ni itagbangba jẹ ohun ti ijọba lodi nitori pe o jẹ orilẹede Musulumi ṣugbọn wọn le ra a ni ile itaja ti ijọba fun laṣẹ.

Lati ọdun 2016 ni ile igbimọ ti kọkọ buwọlu ofin naa ti ẹnikẹni to ba ṣẹ si ofin naa yoo san owo itanra to to milọnu mẹẹdọgbọn dinars owo Iraq.

Ofin yii lodi si tita, kiko wọle ati pipese ọti ṣugbọn o di mimu sẹ l'Oṣu to kọja, ọdun keje lẹyin ti wọn kọkọ buwọlu ofin naa.

Ṣugbọn ko tii ye wa bi ofin naa yoo ṣe fi ẹsẹ mulẹ to tabi boya ile ẹjọ giga lorilẹede yoo yi ofin naa danu.

Ninu ẹjọ to wa niwaju ileẹjọ, awọn ọmọ ẹgbẹ Babylone yari pe ile igbimọ aṣofin kọ lati tẹle iwe ofin orilẹede naa nitori wọn kuna lati faye gba ẹtọ awọn kereje lorilẹede naa.

Wọn ni ofin ọhun tako ofin ijọba, to si jẹ itẹwọgba laarin oṣe kan.

Sarmad Abbas, ni ofin naa yoo sọ tita ọti di ọja okunkun lorilẹede Iraq.

O ni otitọ ni pe iwaasu Musulumi lodi si ọti mimu ṣugbọn "awọn eeyan ni anfani lati pinnu fun ara wọn lati maa tẹle ofin musulumi.