Queen Elizabeth II burial: Àwòrán bí ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth ṣe lọ nìyíí

Awọn alejọ lati orilẹede aka aimoye lo pejọ pọ si ibi isinku Ọbabinrin Elizabeth II ni Ọjọ Kọkandinlogun, Oṣu Kẹsan, ọdun 2022.

Awọn ara ile ọba to fi mọ Ọba Charles lo n rin pẹlu ibanujẹ nitori iku iya rẹ.

Ọmọbabinrin Charlotte ati Ọmọbakunrin George darapọ mọ mọlẹbi wọn lati ṣe ayẹyẹ ikẹyin fun iya-baba- baba wọn.

Ọba Charles ati awọnb mọlẹbi ọba kọkọ wa ọkọ lọ si Westminster Hall ki wọn to to tẹle oku Ọbabinrin Elizabeth naa lọ si abbey.

Awọn alejo to le ni ẹgbẹrun meji 2,000 ni wọn parapọ si Westminster Abbey fun eto isinku naa.

Aarẹ Ilẹ Faranse, Emmanuel Macron, Aarẹ Ilẹ Amerika,Joe Biden ati Olotu Ijọba Canada, Justin Trudeau wa lara awọn adari orilẹede to wa nibẹ.

Olotu ilẹ Gẹẹsi, Liz Truss ati awọn olootun ijọba miran wa nibẹ

Lady Pamela Hicks to ṣiṣẹ gẹgẹ bi alabojuto Ọbabinrin Elizabeth II, wa lara awọn alejo ni Westminster.

Gbogbo aworan lo gba ontẹ.