You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
King Charles III Confirmation Ceremony: Ọba kọrin re ki saa isejọba Ọbabìnrin nibi ayẹyẹ mánigbàgbé
Ọba Charles Kẹta ti gboriyin fun "saa iṣejọba ti ko ni ẹlẹgbẹ" ti Ọbabinrin, lẹyin ti wọn kede rẹ gẹgẹ bi Ọba nibi ayẹyẹ kan to waye ni aafin St James.
Ọba Charles di Ọba alaye tuntun lẹyin ipapoda iya rẹ nibi ipejọpọ kan to waye lọjọ Satide, eyi to fidi rẹ mulẹ bii Ọba.
Ọba naa tun buwọlu pe ki wọn sinku Ọbabinrin ni ọjọ isinmi ti wọn n pe ni Bank Holiday amọ wọn ko tii mọ ọjọ ti yoo jẹ.
Nigba to n ba ipejọpọ igbiimọ awọn ọlọla sọrọ, ba ni iku iya oun jẹ "Adanu ti ko se satunse".
O tẹsiwaju pe "Itunu nla fun mi ni lati mọ ikaanu ti ọpọ eeyan se sawọn arakunrin ati arabinrin mi ati pe irufẹ ifẹ alailgbẹ ati atilẹyin yii ni kẹ na si gbogbo ẹbi mi patapata lasiko adanu yii.:
O wa sọrọ nipa "Isisẹsin alaimọtaraẹninikan" ti Ọbabinrin se, "Iṣejọba iya mi ko lẹgbẹ lasiko rẹ, ifọkansi rẹ ati bo se gbajumọ ohun to yẹ.
"Koda bi a ṣe n kẹdun yii, a dupẹ fun igbe aye olootọ ọhun."
Ọba fikun pe oun yoo "lakaka lati tẹle awokọse ati apẹẹrẹ awunilori" ti iya oun fi ẹsẹ rẹ lelẹ lori "Ojuse ẹru itẹ to wuwo."
Igba akọkọ ree ti iru ayẹyẹ bayii to ti n waye lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin, yoo wa lori ẹrọ amohunmaworan.
Ọba gan funra reẹ ko bawọn peju ni abala akọkọ ipade naa nigba ti igbimọ Ọlọla naa kede rẹ bii Ọba, ninu eyi ti awọn agba oselu aadajọ atawọn osisẹ ọba peju si.
Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìfarajìn Óbabìnrin Elizabeth nígbà ayé rẹ̀ bó ṣe ní "àkókò Ìyá mi gẹ́gẹ́ bí Ọba kò ní ẹgbẹ́ nípa iṣk àti àwọn ètò ìlú."
"Kódà bí a ṣe ń ṣọ̀fọ̀, adúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìgbé ayé rere tí Ọbabìnrin gbé."
Bákan náà ló fi kun wí pé òun yóò gbìyànjú láti tẹsẹ̀ bọ bàtà tí ìyá òun bọ́ sílẹ̀ tí òun yóò sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà rere tó fi lélẹ̀ nídìí ṣíṣe iṣẹ́ sin ìlú.
Ìgbà àkọ́kọ́ rèé láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn tí wọn yóò máa ṣàfihàn ayẹyẹ kíkéde ọba lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán.
Ọba Charles fúnra rẹ̀ kò sí níbi ìpàdé àkọ́kọ́ tí wọ́n ti kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba látẹnu àwọn afọbajẹ èyí tó jẹ́ àpéjọ àwọn àgbà olóṣèlú, àwọn adájọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ ilé Ọba.
Akọ̀wé ìgbìmọ̀ Privy Council, Richard Tilbrook ló kéde Ọba Charles gẹ́gẹ́ bí Ọba, olórí àjọ Commonwealth, olùdáàbòbò ìgbàgbọ́, kó tó kéde "Kí Ọlọ́run dá ààbò bò Ọba."
Gbogbo inú gbọ̀ngàn náà sì wi tẹ̀le tó fi mọ́ àwọn olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ tó wà níbẹ̀ ní ìta ààfin St James.
Atupalẹ iroyin ohun to waye lati ọdọ akọroyin aafin ọba, Sean Coughlan
Ọba tuntun naa sọr imọyi nipa iya rẹ, sugbọn eyi gan kọ ni koko nibayii ti Charles bẹrẹ si foju sọna si isejọba tiẹ lori it.
Niwaju ijoko awọn eekanlu bii agba oloselu atawọn to di ipo ọla mu lawujọ, ba Charles fi iyoku aye rẹ jin fun sise isẹ sin ojuse ọba lori itẹ.
Eto naa lo jẹ idapọ etutu, ede ijilẹ ati afihan isẹ ofin.
Charles ti di olori orilẹede bayii, eyi si ni gbigbe akoso sil ati gbigba akoso lati saa isejọba kan si omiran, pẹlu ibura ati ifontẹlu.
Apoti omi aro ikọwe to lo ni awọn ọmọkunrin rẹ mejeeji, Ọmọọba William ati Ọmọọba Harry fun.
Ikede naa tun fidi rẹ mulẹ pe ọjọ ayẹyẹ isinku alarinrin fun Ọbabinrin yoo jẹ ọjọ isinmi lẹnu isẹ.
Amọ nibi yii ni Ọba tuntun ti se afihan gbigba ojuse rẹ lojuaye, to si seleri lati tẹle awọn apẹẹrẹ ti Ọbabinrin fi lelẹ. O si ti di ilana atẹle to n tẹsiwaju bayi.