Prince Philip: Kíni ìdí tí BBC fi ma ń gbé ìròyìn nípa ikú àwọn kan nínú ẹbí Ọba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?

Too ba ṣakiyesi, oo rii pe awọn oju opo iroyin BBC yatọ l'onii. Iroyin kan ṣoṣo ni awọn ori ayelujara ati amohunmaworan BBC n gbe lera-lera.

Ko si nkan meji to fa a, bi ko ṣe pe ọkan pataki lara awọn agbaagba ninu idile ọba ilẹ Gẹẹsi ti ku.

Ẹni naa si ni ọkọ Ọbabinrin Elisabẹti II, Arẹmọ Philip.

Iku iru eeyan bayii to jẹ agba ninu idile ọba nikan ni BBC le maa fọnrere rẹ bayii.

Awọn mẹta to kù ni Ọbabinrin Elisabẹti II, ọmọ rẹ ọkunrin ti itẹ ọba tọ si, Charles (Arẹmọ ilu Wales), ati ọmọ rẹ, ti ipo ọba kan lẹyin rẹ, Arẹmọ William (Duke ilu Cambridge).

O ṣe e ṣe ki o ti ṣakiyesi pe BBC karamasiki iroyin iku yii ju awọn ileeṣẹ iroyin mii lọ.

Bẹẹni. O ni bo ṣe jẹ.

Kilo mu ki iku awọn ara idile Ọba o jẹ babara fun BBC?

Ọbabinrin Elisabẹti II ni ori ade to ti pẹ ju lori itẹ ni orilẹ-ede UK - o ti wa lori itẹ fun ọdun mọkandinlaadọrin. Oun naa si ni olori orilẹ-ede UK ati orilẹ-ede mẹẹdogun miran.

Bakan naa lo tun jẹ olori ajọ Commonwealth: ajọ kan to jẹ ti orilẹ-ede mẹrinlelaadọta to ti gba ominira. Pupọ ninu wọn lo ti fi igba kan wa labẹ idari orilẹede Britain. Nitori naa, pataki ni Ọbabinrin jẹ ni Britain ati lẹyin odi.

Ti ẹnikẹni ba kú ninu idile ọba Britain, awọn ileeṣẹ iroyin l'agbaye kii fi iroyin nipa rẹ ṣere. BBC si ma n sa gbogbo ipa rẹ, lati ma ṣe aṣiṣe ninu iroyin rẹ, fun idi to dara.

Idi naa ni pe ijọba Britain, nipa ṣẹ awọn ọmọ orilẹ-ede naa. Oun lo n gbọ bukata ileeṣẹ BBC, lati ara owo ori 'licence fee' ti wọn n san.

Ilana gbigbọ bukata yii wa lati ri daju pe BBC ni ominira.

BBC si gbọdọ bọwọ fun awọn to n san owo ori yii, bẹẹ naa si ni nipa nkan ti awọn eeyan fẹ ẹ mọ nipa idile ọba. Eyi si lo ti n 'se fun ọpọlọpọ ọdun nilẹ UK.

Nigba ti iya to bi Ọbabinrin Elisabẹti kú lọdun 2002, o le ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeyan to n ṣe ọfọ, to n lọ, to n bọ niwaju aafin Westminster, fun ọjọ mẹta.

Akọsilẹ wa pe eeyan to le ni miliọnu kan lo duro si ẹgbẹ ọna, ti awọn to to miliọnu mẹwaa si wo o lori amohunmaworan, bi wọn ṣe gbe posi rẹ sinu iboji ni Windsor.

Awọn ileeṣẹ iroyin l'agbaye naa fọnrere iroyin yii.

Eyi ko jẹ iyalẹnu, nitori pe kaakiri agbaye ni awọn eeyan ti ma n fẹ gbọ iroyin nipa awọn ara ile ọba.

Ka ma parọ, iroyin nla ni wọn, BBC naa kii si fi ọwọ yẹpẹrẹ mu wọn.

Akọroyin BBC ninu ile ọba, Jonny Dymond sọ pe okiki awọn ara ile ọba ma n kan ju ti awọn gbajumọ lọ. O ni "o ṣoro lati mọ idi to fi ri bẹẹ, ṣugbọn nkankan ni pe awọn eeyan ma n gbadun lati mọ nipa igbeaye awọn eniyan naa, botilẹ jẹ pe ninu ọkan wọn, iru iroyin bẹẹ ri bakan ni ode oni."

Ireti wa pe ileeṣẹ iroyin BBC l'agbaye ni awọn eeyan yoo wa fun iroyin bẹẹ.

"Iku ẹni to jẹ agba ninu idile ọba jẹ nkan ti awọn eniyan kaakiri agbaye fẹ gbọ. Ọpọlọpọ eeyan si ni yoo tọ wa wa gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Britain, nitori wọn gbagbọ pe lọdọ wa ni wọn ti le ri ẹkunrẹrẹ iroyin - Tarik Kafala (Oludari iroyin fun awọn ẹka BBC ti kii ṣọ ede Gẹẹsi)

Bawo ni BBC ṣe ma n tufọ iku agbalagba ninu idile Ọba?

Nkankan akọkọ ti awọn ololufẹ BBC yoo kiyesi ni pe ibomii ni wọn o ti kọkọ ri iroyin yii. Idi ni pe BBC kii sare fẹ ẹ gbe iroyin, amọ o ma n ṣakitiyan lati ri i pe otitọ ni iroyin ti o ba fi sita.

O kan le jẹ ikede lasan ni BBC yoo ṣe, kii ṣe iroyin yajoyajo.

Bakan naa ni BBC le ma gbe iroyin miran jade ni kete ti o ba kede iku naa, bẹẹ si ni yoo yọ awọn iroyin apanilẹrin kuro ni ori ayelujara rẹ, ati awọn iroyin ori rẹdio ati tẹlifisan.

Amọ ohunkohun ti o ba ri tabi gbọ nipa iroyin naa lẹyin ikede iku nile ọba, oun ni yoo jẹ iroyin akọkọ.

Kinni idi ti Arẹmọ Philip naa fi wa ni ipele kan naa?

Ootọ ni pe Arẹmọ Philip kii ṣe ọba lọla - ọmọ rẹ ọkunrin agba ni yoo jọba - ko si tun lo orukọ oye 'ọba'.

Idi ni pe ni ilẹ UK, obinrin to ba fẹ ọkọ ninu ile ọba, le lo orukọ oye 'Ọbabinrin', ṣugbọn awọn ọkunrin to ba fẹ Ọbabinrin ko le pe ara awọn ni ọba. Awọn ọmọkunrin ile ọba nikan lo le ṣe bẹ ẹ.

Amọ, lati igba ti wọn ti ṣe igbeyawo ni ogunjọ, oṣu Kọkanla, ọdun 1947, ni Philip ti jẹ alabarin fun Ọbabinrin Elisabẹti.

Oun ni alabaro Ọbabinrin to ti pẹ ju lọ ninu itan orilẹ-ede Britain. Ojuṣe kan to ni ni lati ṣatilẹyin fun.

Wọn sun mọ ara wọn debi pe, Ọbabinrin ma n bẹrẹ gbogbo ọrọ apilẹkọ rẹ pẹlu "Emi ati ọkọ mi...".

"Okun mi lo jẹ lati ọpọlọpọ ọdun, o duro ti mi". Bayii ni Ọbabinrin ṣe royin ọkọ rẹ ninu ọrọ to sọ nigba ti igbeyawo wọn pe aadọta ọdun.

"Emi, ẹbi yii, ati ọpọlọpọ orilẹ-ede jẹ ẹ ni gbese to tobi ju nkan to le beere fun, tabi ti amọ."

Njẹ o rii pe o sẹ pataki lati gbe iroyin nipa iku rẹ?

Dymond sọ pe "gbajumọ agbaye ni, ọkan ṣoṣo iru ẹ".