Ìgbà máàrún tí ọ̀rọ̀ Buhari dá awuyewuye sílẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lati ọdún bíi mẹta tí ààrẹ Muhammadu Buhari ti wa lori aleefa, o ti ṣe awọn ohùn manigbagbe kan bẹẹ sì ní o sọ awọn ọrọ manigbagbe naa.

Laipẹ yii o sọ wípé àwọn ọ̀dọ̀ Nàìjíríà ko fẹ nkan ṣe, tí ọrọ náà sì mú ariwisi ọtọọtọ wa.

Ẹ jẹ ki a wo awọn igba miran to sọ ọrọ ni ilu okeere tó dá awuyewuye silẹ, pàápàá jùlọ lórí ẹrọ ayélujára.

"Yara inu laaye Aisha wa"

Nigba to se abẹwo kan si orileede Germany, Aarẹ Buhari sọ fun olootu ijọba orileede naa, Angela Merkel, pe'' iyara inu laaye iyawo oun wa.''

Aisha Buhari ti saaju sọ wi pe bi ọkọ ohun ba gbe apoti ibo,oun ko ni dibo pẹlu bi nnkan se'n lọ ni ijọba rẹ.

Titi di bi a se nsọrọ yii, awọn ọmọ Naijiria ko gbagbe ọrọ naa.

"Loot ni iwa jẹgudujẹra gbil ni Naijiria"

Olootu ijọba ilẹ̀ Gẹẹsi, David Cameron sọ nibi ipade kan to da lori iwa jẹgudujẹra, pe orilẹede Naijiria wa lara awọn ti o gbajugbaja ninu iwa naa.

Ọrọ naa bi awọn ọmọ Naijiria ninu, sugbọn eyi to da awuyewuye silẹ ni esi Aarẹ Buhari pe lootọ ni Naijiria gbajugbaja ninu iwa jẹgudujẹra.

"Awọn ọdọ ko fẹ nkan se"

Eyi ni ọrọ to sẹ̀sẹ̀ sọ to mu ki ọpọ ọdọ Naijiria faraya lori ikanni Twitter.

Alaye ni Buhari ni oun n ṣe lori ibeere kan ti wọn fi sọwọ sii nibi ìpàdé Commonwealth ní Westminster lọjọru, sugbọn ọrọ to sọ ko dun mọ awọn ọdọ Naijiria nínú, o ni ''won o fe nkan se''

Awọn eyi to sọ nile

Pẹlu bi aibalẹ ọkan se wa, nitori ija awọn darandaran ati awọn agbẹ ni ipinlẹ Benue, Aarẹ Buhari lọ se ipade pẹlu awọn alenulọrọ ni ipinlẹ naa.

Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ nigba to sọfun awọn to wa ni ikalẹ pe, oun ko mọ pe ọga ọlọpaa, Ibrahim Idris kọ etiikun si aṣẹ t'oun pa, pe ko k'ẹru rẹ lọ si Benue.

AfCFTA: Naijiria k lati t'ọwọ bọ iwe ilana okoowo tuntun fun Afrika

Ohun ti ọpọ eniyan sọ ni wi pe bi Naijiria ti o jẹ ọkan gboogi lara awọn orilẹede ti karakata rẹ muna doko ju nilẹ Afrika, bi ko se kopa jẹ ipenija fun adehun naa.

Lẹyin ti ipade naa pari ni Rwanda, ti wọn si ti f'ọwọ si iwe tan, ni Aarẹ Buhari wa se akojọpọ igbimọ kan nibi ipade igbimọ alasẹ ijọba orilẹede Naijiria.

O ni ''o yẹ ki ijọba tubọ se agbeyẹwo atubọtan titọwọ bọ iwe adehun naa lori ọrọ aje ati eto aabo l'orilẹede Naijiria.''