You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Commonwealth: Ohun méje pàtàkì tó yẹ ní mímọ̀
Àwọn olórí àjọ commonwealth ń se ìpàdé ní London báyìí. Kókó méje rèé tó yẹ kóo mọ̀ nípa àgbáríjọpọ̀ àwọn orílẹ̀èdè tí o kò tíì mọ̀ tẹ́lẹ̀.
1) Idá mẹ́ta àwọn orílẹ̀èdè àgbáyé ló wà níbẹ̀
Idá bílíọ̀nú meji ènìyàn àti ààbọ̀ nínú bílíọ̀nú méje ó lé díẹ̀ èèyàn tó wà lágbàáyé ló ń gbé àwọn orílẹ̀èdè náà
Àwọn Orílẹ̀èdè mẹ́tàléláàdọ́ta lágbàáyé ló ń kópa níbẹ̀. Orílẹ̀èdè India ló tóbi jù nínú àwọn orílẹ̀èdè tó ní èrò tó pọ̀ jùlọ, sùgbọ́n mọ́kànlélọ́gbọ́n nínú àwọn orílẹ̀èdè náà ló ní àpapọ̀ èèyàn tótó mílíọ́nù kan àti ààbọ̀ tàbí kó dín díẹ̀.
2) Awọ̀n ọmọ ẹgbẹ́ commonwealth kan kò sí lábẹ́ àkóso ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
Ọdún 2009 àti 1995 ní Mozambique àti Rwanda darapọ̀ mọ́ àjọ Commonwealth bẹ́ẹ̀ni wọn kò ní àjọsepọ̀ tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì láti ipasẹ̀ ìmúnisìn tàbí ìlànà òfin.
Bákanáà ni àjọ Commonwealth ti pàdánù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ sẹ́yìn. Robert Mugabe mú orílẹ̀èdè Zimbabwe kúrò nínú àjọ yìí lọ́dún 2003 lẹ́yìn tí wọn fòfin de orílẹ̀èdè náà nítorí ẹ̀sùn síse màgòmágó ìbò.
3) Ọbabìnrin ni olórí ní orílẹ̀èdè mẹ́rìndínlọ́gún péré
Orílẹ̀èdè mẹ́rìndínlógún ni Ọbabìnrin Elizabeth keji jẹ́ olórí fún nínú àjọ Commonwealth.
Orílẹ̀èdè mẹ́fà ló ní ọba tiwọn nínú àjọ Commonwealth. Àwọn Orílẹ̀èdè náà ni Lesotho, Swaziland, Brunei Darussalam, Malaysia, Samoa àti Tonga.
Orílẹ̀èdè mọ́kànlélọ́gbọ́n sì ló jẹ́ orílẹ̀èdè olómìnira.
4) Commonwealth tóbi púpọ̀
Àwọn orílẹ̀èdè tó wà nínú àjọ Commonwealth kó ìdá mẹ́rin nínú gbogbo ilẹ̀ àgbáyé.
Orílẹ̀èdè Canada ló tóbi jùlọ nínú àjọ Commonwealth, òun náà sì ló tóbi sìkejì nínú àwọn orílẹ̀èdè lágbàáyé.
Bákánáà ni orílẹ̀èdè India àti Australia náà tóbi sìgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀èdè bíi Pacific Island, Nauru, Samoa, Tuvalu and Vanuatu, pẹ̀lú Dominica and Antigua àti Barbuda lágbègbè Carribean.
5) Àjọ Commonwealth pààrọ̀ orúkọ rẹ̀
Lọ́dún 1949 ni wọ́n da àjọ Commonwealth tuntun sílẹ̀ nígbà tí wọ́n yọ orúkọ ilẹ̀ Gẹ́ẹ̀ọsì kúrò, tí wọ́n sì yọ àmà ajọsepọ̀ pẹ̀lú adé orí ọba kúrò nínú rẹ̀.
Àwọn orílẹ̀èdè tó bẹ́rẹ̀ àjọ Commonwealth ni Australia, Canada, India, New Zealand, Pakistan, South Africa, Sri-lanka àti United Kindom.
2013 ni orílẹ̀èdè Gambia kéde pé òun kò sẹgbẹ́ mọ́ nítori ó ní ìlànà náà jẹ mọ́ ti amúnisìn.
6) Ìlú Ọba sì ló ní ọrọ̀ ajé tó tóbi jù nínú àjọ Commonwealth
Àwọn orílẹ̀èdè tí ọrọ̀ ajé wọn tóbi nínú àjọ Commonwealth ni United Kindom, India àti Canada.
Àwọn orílẹ̀èdè tí ọrọ̀ ajé wọn kéré nínú àjọ Commonwealth ni Tuvalu, Nauru àti Kiribati
7) Commonwealth ju ẹyọ kan lọ
Ọdún 1991 ni àwọn ọmọ̀ ẹgbẹ́ àjọ ìsọ̀kan ílẹ̀ Russia dá ìgbìmọ̀ orílẹ̀èdè olómìnira sílẹ̀ nínú àjọ Commonwealth.