Biyi Otegbeye: Ìrẹ́jẹ àti ìrìn ìdọ̀tí wà nínú APC l‘Ogun, ni mo ṣe lọ sí ẹgbẹ́ òṣèlu ADC

Oludije sipo gomina labẹ asia ẹgb oselu ADC nipinlẹ Ogun, Olubiyi Oladipupo Otegbeye ti salaye ọpọ ohun to gbe wa sidi oselu ati idi to se fẹ dije du ipo gomina nipinlẹ Ogun.

Otegbeye, lasiko to n fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu BBC Yoruba ni irẹjẹ pupọ lo wa ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ogun nitori ọpọ ohun ti ko bojumu lo waye lasiko ibo abẹnu lati yan oludije sipo gomina ti yoo soju ẹgbẹ naa ninu ibo 2023.

Otegbeye, tii se ọmọ bibi ilu Ilaro, lẹun idibo Ogun West ni kaka ki ohun si maa rin irin idọti ninu ẹgbẹ oselu APC, lo mu ki oun ko aasa oun lọ sinu ẹgbẹ oselu ADC, tii se ẹgbẹ to mọ.

"Ipe Ọlọrun ni ipe mi sinu oselu, ojuse mi si ni lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun nitori pe ẹkun idibo mi n pohungbẹ idagbasoke lo mu mi wọnu oselu.

Amọ bi ibo abẹnu lati yan oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ ẹgbẹ oselu APC se lọ ku diẹ kaa to, a si pe akiyesi awọn alasẹ loke lọhun si sugbọn wọn ko se nkankan si.

Awa mẹfa la dibo abẹnu pẹlu gomina to wa lori oye lọwọ lọwọ, eyiun, Dapo Abiodun, amọ wn ni awa marun ko ni ibo kankan, Abiodun nikan lo ko gbogbo ibo naa.

Koda, awa mẹrin pe ẹjọ kotẹmilọrun lori esi ibo abẹnu naa sugbọn mo finu findọ fi ẹjọ naa silẹ lati lọ dije ninu ẹgbẹ oselu ADC."

Nigba to n sọrọ lori ihuwasi gomina Dapo Abiodun, Otegbeye ni "Bi Abiodun se n bu ramuramu, lo ipo agbara ko mi wa nitori a ti ri awọn eeyan to wa nipo agbara sẹyin, ti wọn se ju bẹẹ lọ.

Abiodun ti ko awọn ọba ladelade wa laya jẹ, o ti sọ wọn di oloselu, se lo n ko wọn lẹyin lọ sode oselu, o kan ku diẹ, ki wọn maa de fila ipolongo ibo Abiodun ni."

Bakan naa ni oludije sipo gomina fẹgbẹ oselu ADC ọhun salaye ajọsepọ to wa laarin ohun ati gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Ibikunle Amosun ati ọpọ ohun ribiribi to fẹ gbe se lori oye, to ba wọle sipo gomina ipinlẹ Ogun.