You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aje Games: Eré ayò ọrọ̀ ajé ló ń wá ọ̀nà àbáyọ sáwọn ìṣòro tó ń bá Yorùbá fínra
Ni ilẹ Yoruba, wọn a ni ere la n fi ọmọ ayo se.
Amọ laye ode oni, owe yii ko fẹ ba igba mu mọ nitori ayo ti kọja ere sise lasan bayii.
Idi ni pe oniruuru awọn ọpọn imọ lori ayelujara, to fi mọ ayo gan, lo ti wa lori atẹ bayii.
Lara ere ayo yii si la ti lee ri ọgbọn gidi kọ, ta si tun mọ nipa asa ati ise abinibi wa nilẹ Yoruba.
- Ṣé o rántí eré òṣùpá? Wo èré ìdárayá èyí tó yẹ fún àárọ̀ kùtù àti èyi tó wà fún òṣùpá
- Adeoye Fawaz rèé ''Conductor'' ọmọ abẹ́ ''Bridge Oshodi'' tó fí gbọ̀ọ̀rọ́ jẹkà nidi eré Chess
- Bojú bojú o... Ta ló rántí?
- Kò sí ọmọ tó yẹ kó fìdírẹmi mọ́ nínú ìdánwò- Salami
- Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ
- Ọdún mẹ́ta gbáko ni mo fí ṣé ìgbáradì láti fi di "National Chess Master" -Tanitoluwa
- Yorùbá, ọmọ ọdún mẹ́jọ tà ọmọ òyìnbò yọ nínú ayò Chess l‘Amẹrika
Ọkan ninu awọn ọpọn imọ yii ni Ayo ọrọ Aje, eyi to n se agbelarugẹ asa, ise ilẹ Yoruba.
Bakan naa lo tun n wa ojutu si ọpọ isoro to n ba orilẹede wa finra.
Bawo ni ere Ayo ọrọ Aje se waye:
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ẹni to se agbekalẹ ọpọ ayo ọrọ aje naa, Tobiloba Ogunngbemi ni ọpọn naa kii se ere lasan.
Amọ o wa fun imọ lati mọ asa, igbagbọ ilẹ Yoruba ati orisa.
O ni awọn isoro kan wa ni awujọ wa bii airisẹse ọdọ, aisi ẹkọ ile, aisi ẹkọ ibaraẹnigbe ati okoowo.
Ọna lati le kọ awọn eeyan ni ọna idokowo si lo se okunfa agbekalẹ ere ayo ọrọ aje.
O si gba oun to ọdun mẹfa, ki oun to le gbe kalẹ.
Ki lo wa ninu ọpọn ayo ọrọ aje:
Ogungbemi ni gbogbo awọn nnkan bayii lo wa ninu ere ayo naa lati se idanilẹkọ fawọn ọmọ Kaarọ oojire.
Bakan naa ni awọn ọna abayọ si gbogbo awọn isoro to n bawọn ọmọ ilẹ Kaarọ oojire finra wa ninu rẹ pẹlu.
Awọn ohun ta le se tabi mu lo lati awọn ara asa wa tun wa ninu ọpọn ayo naa, kawọn ọdọ le mu lo fun ẹkọ lati tun awujọ wa se.
Bawo ni a se n ta ayo ọrọ aje:
Ogungbemi ni ni aarin ọpọn ayo ọrọ aje ni ọpọn ifa wa, ori rẹ si ni awọn ilu ti yii kaakiri.
“Gbogbo ilu nilẹ Yoruba ati awọn eeyan ti ori sa da naa wa nibẹ.
Awọn orisa ta n ran nisẹ si ọdọ olodumare naa wa nibẹ.
Bakan naa ni origun mẹrẹẹrin agbaye wa, nibi ti awọn ọmọ Yoruba wa.
Irinajo naa wa nibẹ, ẹkọ ile, iwa ọmọluabi, aabo ara wa ati Aarẹ Ọna Kakanfo naa wa nibẹ.
Owo ẹyọ si ni wọn fi n da ayo naa, ohun si ni yoo sọ onka ta ba da boya meji ni abi mẹta.”
Awọn wo lo le lo ọpọn ayo ọrọ aje:
Oludasilẹ ayo ọrọ aje salaye pe gbogbo idile ni ere ayo naa wa fun.
Tọmọde tagba, ọkunrin ati obinrin si lo ni wọn le fi ere ayo naa sere.
O ni eeyan mẹjọ lo le kopa lati ta ayo naa, ti wn si ni alakoso wọn.
Eeyan meji si lo sọ pe o kere julọ lati kopa ninu ere ayo naa.
O salaye pe ọpọ awọn onimọ lo ti yẹ ayo naa wo, ti wọn si ri pe kii se ere lasan.
Bakan naa lo n kọ awọn eeyan ni ẹkọ, paapa awọn ọmọ Oodua lati maa gbe asa wa larugẹ
O wa seleri pe laipẹ ni ere ọpọn ayo ọrọ aje yoo wa lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ eeyan kọọkan lati lo.