You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Timothy Adegoke: Èrò agbẹjọ́rò olùpẹ̀jọ́ àti olùjẹ́jọ́ ṣe ọ̀kan lórí àṣẹ́ adájọ nípa ìgbẹjọ̀ ikú olóògbé
Awọn agbẹjọro fun ẹbi akẹkọọ OAU ti wọn ba oku rẹ ni ile itura Hilton, Timothy Adegoke ati eyi to n ṣoju Maye Ile Ife, Ọmọọba Rahmon Adedoyin, ti fesi si igbesẹ ile ẹjọ giga Abuja lati yọwọ ninu ẹjọ naa.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ọtọọtọ ti wọn se pẹlu ileeṣẹ BBC Yoruba lẹyin ikede ile ẹjọ giga Abuja pe ki wọn gbe ẹjọ naa pada si Osun, awọn mejeeji ni igbesẹ naa tẹ awọn lọrun.
Amofin Adekilekun to n ṣoju mọlẹbi Adegoke sọ pe inu awọn dun ati pe awọn ṣẹsẹ bẹrẹ si ni ri apẹrẹ pe awọn yoo ri idajọ ododo gba lori ọrọ naa ni.
- Ìjọba àpapọ̀ yọwọ́ kúrò nínú ẹjọ́ tó ń bá Rahmon Adedoyin àtàwọn afurasí míì ṣe lórí ikú Adegoke
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
- A kò fi ẹbí Timothy sílẹ̀, à ń gbiyànjú pé kí wọ́n dá ẹjọ́ náà padà sí Osun dípò Abuja ni- Agbẹjọ́rò Adekilekun
- Báméjì lọ̀rọ̀ Sunday Igboho lè já sí bí ó bá yanjú ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Benin republic - Abubakar Malami
- Ìjọba le gbé ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari lọ Amẹ́ríkà láti lọ jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì pẹ̀lú Hushpuppi - Malami
Adekilekun fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni ile ẹjọ gbe igbesẹ lati da igbẹjọ pada si ile ẹjọ ipinlẹ Osun.
Ile ẹjọ giga lo yẹ ki wọn gbe ẹjọ lọ, kii se ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ - Adekilekun
''Ṣe ẹ mọ pe ohun taa n sọ tẹlẹ ni pe ileẹjọ giga tijọba apapọ ko lasẹ lati gbẹjọ yii ni Abuja. Nisinsinyii ile ẹjọ naa ti wa gba siwa lẹnu pe lootọ ni.''
O tubọ se alaye pe, iru ẹjọ to wa nilẹ yii, kii se ile ẹjọ giga apapọ lo maa n gbọ, bi kii se awọn ile ẹjọ giga nipinlẹ ti isẹlẹ ba ti waye.
''Ile ẹjọ giga wa ni Abuja lo jẹ ti olu ilu ilẹ wa FCT, eleyi yatọ si ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Abuja.''
''Wọn yatọ si ara wọn. Ile ẹjọ giga lo yẹ ki wọn gbe lọ, kii ṣe ile ẹjọ giga apapọ.''
Ko ru mi loju bayii pe idajọ ododo yoo wa lori iku Adegoke:
Lori boya wọn ti ni aridaju bayi pe idajọ ododo yoo waye lori ẹjọ yii, agbẹjọro Adekilekun sọ pe ko ru oun loju pe idajọ ododo yoo waye.
''Nigba taa kọkọ bẹrẹ lati gbe ẹjọ yẹ kuro ni Abuja, o kọkọ lọ tikọ diẹ, wahala wa, awọn eeyan...ọwọ wọ ọ. Wọn ko fẹ ki ẹjọ naa kuro nibẹ.''
''Amọ bayi ti ile ẹjọ ti se ohun to yẹ ko ṣe, ẹ jẹ ki akun fun igbagbọ ninu Ọlọrun, ki a si ni igbagbọ ninu orilẹede wa Naijiria.''
Ipa ti ajafẹtọmọniyan Falana ko ninu dida ẹjọ pada si Osun ko kere:
Amofin Adekilekun ko ṣalai mẹnu ba ipa ribiribi ti agba ọjẹ agbẹjọro nii Femi Falana ko ninu dida ẹjọ naa pada si Osun.
Adekilekun ni Falana gan ti kọkọ fi iwe ransẹ si ọga ọlọpaa lati bi ogunjọ oṣu kinni lori ibeere naa ṣugbọn wọn ko ṣe nkankan le lori.
''Sugbọn a dupẹ , ki ọkunrin ri ejo, ki obinrin pa ejo, ki ejo sa ma ti salọ. Adupẹ lọwọ baba wa, ọga wa Femi Falana pẹlu ipa takuntakun ti wọn ko lori ọrọ yii.
Bi a ko ba gbagbe, Femi Falana ti ṣaaju fi iwe ranṣẹ sileeṣẹ ọlọpaa ati adajọ to n gbẹjọ naa ni Abuja, pe ko tọ lati gbẹjọ yi ni Abuja.
Falana to tun jẹ ajafẹtọmọniyan sọ pe, niwọn igba ti wọn ko da ẹsẹ ti wọn n sẹjọ rẹ ni Abuja, ohun to yẹ ni ki wọn ṣe ẹjọ ni Osogbo, tii se olu ilu ipinlẹ Osun.
Ko si idi fun wa lati tako asẹ ijọba to ni ka gbe ẹjọ lọ si Osun - Agbẹjro Adedoyin
Amofin Kunle Adegoke, tii se agbẹjọro fun ikọ afurasi olujẹjọ naa sọ pe, awọn ko ni idi kankan lati tako igbesẹ ijọba lati gbe ẹjọ naa kuro lati Abuja pada si Osun.
O ni ṣaaju naa lawọn ti n sọ fun awọn ọlọpaa pe ko tọ lati gbe ẹjọ naa lọ si Abuja dipo ipinlẹ Osun to ti ṣẹ wa.
O ni olupẹjọ ijọba ko ṣe ẹjọ mọ lori ọrọ yii ati pe wọn ko ti tu onibara rẹ silẹ.
''Ireti wa ni pe bi wọn ba gbe ẹjọ pẹlu onibara wa lọ si Osun, yoo bojumu pupọ''