You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Africa Eye: Wo aburú àti ìpalára tí òògùn olóró Kush tuntun n ṣé fún àwọn ọdọ́
Ikilọ pataki: Awọn aworan to le fa iporuru ọkan, afihan oogun oloro lilo ati ọrọ nipa awọn to n gbero lati se ara wọn ni ijamba tabi gbẹmi ara wọn wa ninu fidio yii.
Ki ni naa n ran kaakiri ni orileede Sierra Leone, Kush si ni wọn n pe orukọ oogun oloro olowo pọọku naa.
Oogun oloro yii ti n ṣe akoba fun ọpọ agbegbe ileto ati ilu ni Sierra Leone.
Ileeṣẹ iroyin wa BBC ti gbọ nipa ọpọ awọn ọdọ to se ara wọn ati lomiran lese tabi ki wọn tiẹ pa ara wọn nipa lilo oogun oloro yii.
Awọn oṣiṣẹ ilera lawọn ile iwosan olu ilu Freetown sọ pe itọju nitori Kush ni awọn ida aadọrun ọkunrin to n wa si ọdọ awọn n gba.
Ogun nla lorileede naa n koju lati le koju ajakalẹ ti oogun oloro yi n koba wọn ni Sierra Leone.
Pẹlu bi oogun yi ṣe n ja rainrain akọroyin Africa Eye Tyson Conteh ṣe iwadii oogun oloro yi to si n beere ohun ti Sierra Leone le se lati fi koju oogun oloro yii.
Ki lo n jẹ Kush:
Kush ni ewe gbigbẹ ti wọn fọn oogun oloro si lara, eyi ti owo rẹ ko wn pupọ fun awọn ọdọ lati mu.
Orukọ miran ti wọn tun n pe Kush yii ni Spice.
Oogun oloro yii ti di ọba to gbajumọ laarin awọn ọdọ, to si ti bori awọn oogun oloro miran bii Tramadol.
Ipa ti Kush n ni lori awọn ọdọ:
O n ya awọn ọdọ ni were loju ẹsẹ
Awọn ọdọ n pa ara wọn laipe ọjọ
Awọn dọ ni Kush maa n mu idunnu ati ayọ de ba awọn.
Wọn maa n fi ara gbọgbẹ nigba ti wọn ba fa Kush sori
Awọn ọdọ lọkunrin maa n wa ohunkohun ti wn yoo ta kiri lati wa owo ti wọn yoo fi ra Kush
Awọn ọdọ lobinrin naa maa n se isẹ asẹwo lati ri owo ra oogun oloro Kush yii.
Oogun oloro yii tun maa n ti awọn ọdọ lati huwa ọdaran
Kush maa n fun awọn ọdọ lọkunrin ni agbara gidi lati ba ọpọ obinrin ni ibalopọ lai rẹ rara.
Bakan naa lo tun maa n mu itiju kuro lara awọn obinrin to n se owo nabi.
Isẹ wo ni awọn ọlọpaa ti se lati doola awọn dọ lọwọ mimu oogun oloro yii:
Iwadii BBC African Eye fihan pe isẹ nla ni ileesẹ lọ orilẹede Sierra Leone n se lati doola ẹmi awọn ọdọ yii lọwọ oogun oloro to n da ẹmi wọn legbodo laipe ọjọ.
Lara irufẹ igbesẹ ti wọn n gbe ni bi wọn se n gbẹsẹle awọn apo oogun oloro Kush yii lọdọ awọn ontaja rẹ, ti wọn n ta fun awọn ọdọ.
Bakan naa ni ileesẹ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni orilẹede naa tun n se idanilẹkọ fun ọpọlọpọ awọn ọdọ ti wọn mu pe wọn n mu oogun oloro Kush yii, ki wọn le yi pada si rere.
- Femi Falana kò gba kọ́bọ̀ fún ìgbẹ́jọ́ Timothy Adegoke àmọ́ aráàlú ń dáwó jọ - Ẹ̀gbọ́n olóògbé
- "Ọ̀nà àtijẹ lára Nàíjíríà ní orílẹ̀èdè Benin ń wá tó ṣe fi oṣù mẹ́fà kún àhámọ́ Sunday Igboho"
- 'Ìyá Ilorin' àti DPO kó sí páńpẹ́ NDLEA, oògùn olóró ràǹbadẹ̀ ni wọ́n ká mọ́ wọn lọ́wọ́
- "N kò mọ ẹni tí ọkọ́ mi ṣẹ̀, tí wọn fi ṣa ní àdá, tó sì gba ibẹ̀ kú lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án"