Africa Eye: Àṣírí ìhà tí ìjọba kọ sí àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì Nàìjíríà rèé

Kii ṣe tuntun ni ohun ti oju awọn to ti ṣiṣẹ fẹyinti n ri lorilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ awọn oṣiṣẹfẹyinti yii to jẹ agbalagba ti awọn miran si ti darugbo ni wọn n fi ẹtọ owo ifẹyinti wọn dun wọn.

Koda, ọpọlọpọ lo ti ku sẹnu jija fun ẹtọ wọn yii lai jẹ anfani owo wọn ki wọn to ku.

Oniruuru ni awọn idi ti ko lori tabi lẹsẹ ti awọn eeyan ni wọn n fun awọn.

Iwadii ikọ aṣewadii BBC Africa Eye tu aṣiri pe o yẹ ki wọn san owo fun awọn oṣiṣẹfẹyinti yii nipasẹ awọn oṣiṣẹ ọba kan ṣugbọn wọn n ko owo naa jẹ.

Fidio iwadii ikọkọ ṣafihan bi awọn oṣiṣẹ ijọba ọhun ṣe maa n bere fun owo ọtọ lọwọ awọn to ti fẹyinti lati ba wọn gbe iwe wọn jade. "Shrine ni wọn n pe ọfiisi ara wọn tori awọn nkan ikọkọ to n waye nibẹ.

Oṣiṣẹfẹyinti kan lo yọlẹ ya fiimu iwa ti wọn n hu ni ọfiisi naa.