Ekiti 2022: Fayemi ni Bàbá ìsàlẹ̀ gbogbo APC ni Ekiti, kìí ṣe fún èmi nìkan- Abiodun Abayomi Oyebamiji

Ogbeni Abiodun Abayomi Oyebamiji ni ẹgbẹ All Progressives Congress kede pe yoo ṣoju wọn lati dije du ipo gomina ipinlẹ Ekiti.Ta ni Abiodun Oyebamiji tí APC dìbò yàn bí olùdíje gómìnà l'Ekiti

Oyebamiji ni awọn mii pe ni oludije ti gomina Fayemi to n tukọ ipinlẹ Ekiti bayii fami ororo yan.

Bẹẹ naa ni oun funra rẹ si sọ fun BBC pe Fayemi kii ṣe baba isalẹ fun oun nikan rara bikoṣe fun gbogbo ol;oselu APC ni Ekiti pe fun idi eyi kii ṣe pe oun nikan ni Fayemi fọwọsi.

O menuba koko mẹrin ti Fayemi n beere lọwọ ẹnikẹni to ba fẹ gba ipo lọwọ rẹ ninu ididbo gomina ódun yii.

Bakan naa ni Oyebamiji menuba awọn igbesẹ ti ẹgbẹ yoo gbe lati bori wahala to wu ko wa nilẹ lẹyin ididbo ẹgbe APC ni Ekiti to kọja yii.

O tun ni ẹgbẹ naa ko le daru ni Ekiti