Sierra Leone Tanker explosion: Ìjàmbá iná sọ lásìkò tí táńkà epo àti ọkọ̀ akérò forí sọra

O kere tan, eeyan mejilelaadorun lo ti farapa ninu iṣẹlẹ ijamba ina kan to wáyé nilu Freetown, lorile-ede Sierra Leone.

Ijamba ina náà lọ waye nigba ti ọkọ akẹru ati tanka epo bentiroolu fi ori sọ ara wọn.

Opopona Bai Bureh ladugbo Wellington nilu Freetown tii ṣe Olu ilu Sierra Leone ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ọpọlọpọ eeyan lo sare lọ bu epo bentiroolu nigba ti iṣẹlẹ naa waye, àmọ́ sadede ni iná sọ, ti ọpọ eeyan si ha síbẹ̀.

Iroyin naa ni ṣe ni wọn gbe awọn eeyan to farapa sile ìwòsàn kaakiri ìlú Freetown.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Sierra Leone, Julius Maada Bio wa ni Scotland nibi to ti n ba wọn peju sibi ipade apero nípa oju ọjọ lagbaye COP26, lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

Àmọ́ loju opo Twitter rẹ lo ti n daro àwọn eeyan to fori sọta iṣẹlẹ naa.

"Adanu ẹ̀mí to ba ni lẹru ni iṣẹlẹ naa, ijọba mi yoo sa ipa gbogbo lati ṣe iranwọ fáwọn eeyan to fori sọta ijamba ina náà."

Olootu ìjọba ilu Freetown, Yvonne Aki-Sawyer ni oku eeyan mẹrin lo si wa nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Awọn ọlọ́pàá ti n ṣe iranwọ fun àjọ to ń ṣe akoso ijamba lorilede Sierra Leone lati doola ẹ̀mí ninu ijamba ọhun.