Seyi Makinde: Ìfẹ́ Ọlọ́run ni mo fẹ́ kò ṣẹ lórí ayé mi lórí ìbò 2023

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde salaye pe oun setan lati pari aawọ pẹlu awọn igun PDP to n fi apa janu nipinlẹ Oyo.

Gomina Makinde kede ọrọ yii lasiko to kopa lori akanse ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Yoruba.

Makinde ni oun setan lati wọna abayọ sawọn ibi to ba ku si, ki aawọ le pari laarin awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to n binu.

Lori ibasepọ rẹ pẹlu gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayodele Fayose, Makinde ni ko si aawọ kankan laarin oun ati agba oselu naa.

Gomina Oyo ni awọn ọmọ ẹgbẹ kan lo maa n da aarin awọn asaaju ẹgbẹ ru nitori ohun ti wọn yoo ri jẹ nibẹ.

Nigba to n sọrọ lori boya yoo du ipo gomina fun saa keji tabi du ipo aarẹ lọdun 2023, gomina Makinde ni ifẹ Ọlọrun ni oun ko fẹ ko sẹ lori aye oun.

O ni oun sẹsẹ ba isẹ tawọn eeyan ipnlẹ Oyo gbe fun oun de idaji ni, o si di ọdun 2023 ki oun to mọ igbesẹ ti Ọlọrun fẹ ki oun gbe.