You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ademuyiwa Wikipedia: Wọ́n fi ìgò lé mi, mo sì ń bá ìwọ̀sí pàdé lórí ìwé títà lójú pópó
Yoruba ni ẹni ti ko ba se bii alaaru ni Oyingbo, ko le se bii Adegboro lọja ọba, bẹẹ si ni ẹni ti yoo la, oju rẹ yoo ri to.
Awọn owe yii si la le sọ pe o jẹ mọ igbe aye ọkunrin kan, Adekola Ademuyiwa, to n ta iwe lọna ara ọtọ, nipa lilo awada, ẹfẹ ati ọpọlọ lati mu ki aje bu igba jẹ.
Idi si ree ti awọn onibara rẹ fi n pe ni Wikipedia.
Ademuyiwa, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to sun de idi isẹ naa ni ẹnikan lo sọ fun oun pe isẹ idọti ni oun yoo se jẹun lati fi la.
- Ọ̀rá ‘Pure Water‘ àti àlòkù aṣọ ni mo fi ń ṣe aṣọ òkè láti pèsè ohun mère-mère - Adejoke Lasisi
- Ìpèníjà ojú kò ní kí ń má ṣiṣẹ́ ‘DJ’ - Etu Sodiq Omotayo
- 'Oníṣègùn, alágbo, aláàfáà, aládurà, gbogbo èèyàn ló ń wá ra ìkòkò àmọ̀ wa'
- 'Làákàyè ẹni tó ń darí eré ju t'awọn òsèrè lọ'
- Atagitá Fẹ́mi Aníkúlápó-Kútì bá obìnrin lọ l‘Amẹ́rika
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Ẹ wo àwọn gbajúmọ̀ òṣèré tíátà tó jogún eré ṣíṣe lọ́dọ̀ òbí wọn
O fikun pe inu oun maa n dun lati kiri lọ soju popo lọ ta iwe, eyi to rọrun fun oun lati se tori ko si ibi ti oun kii rin ẹsẹ de.
Ademuyiwa, ẹni to gbe oriyin fun iyawo rẹ to ti di oloogbe fun atilẹyin rẹ lati maa ta iwe naa, tun salaye pe oun maa n pa to ẹgbẹrun mẹwa si mẹẹdogun naira lojumọ ti ọja ba ya daadaa.
Nigba to n sọ awọn iriri rẹ nidi okoowo naa, Ademuyiwa ni obinrin kan ti oun fẹ fi se aya lẹyin iku iyawo oun, tabuku oun lori iwe tita naa.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa Da Rocha? Olówó yalumọ àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yorùbá
- Mọ̀ sií i nípa Oba Yesufu Asanike , Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Oyinkan Abayomi, akọni obìnrin tó fi ìfẹ́ pa orúkọ ọkọ kejì dà sí ti ọkọ àárọ̀
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Wo ìgbẹ̀yìn àwọn ọlọ̀tẹ̀ Yorùbá tó ran Fulani lọ́wọ́ láti kógun ja ìlú Osogbo
- Ìtàn ìgbé ayé Bode Thomas rèé, ó kọ́ wa láti máa kó ẹnu wa ní ìjánu
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
Bakan naa lo ni ẹnikan ti fi igo le oun ri lasiko ti oun npolowo iwe tita fun, o lẹ igo mọ oun amọ Ọlọrun ni ko jk ki igo naa ba oun.
Adekola Ademuyiwa wa rọ awọn ọdọ lati jara mọ isẹ, lai se ọlẹ nitori oun ti rin lati Iyana Ipade de Ikotun ri nitori iwe tita ati lati ri ti aje se.