You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pańpẹ́ ọba mú pàsítọ̀, babaláwo àti àwọn mẹ́ta tí wọ́n ká ara ènìyàn mọ́ lọ́wọ́
Pàsítọ̀ kan ni ìlú Kajola ni ẹ̀ba Osogbo tí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Osun, Olagunju Adetunji ni àwọn ọlọ́pàá fi ojú rẹ̀ hàn fáwọn oníròyìn nítorí wọ́n ká ọwọ́ àti ẹsẹ̀ ènìyàn mọ lọ́wọ́.
Yàtọ̀ sí pàsítọ̀ ẹni ogójì ọdún náà, wọ́n tún sàfihàn Rasheed Ajani, Saka Akeem, Abiodun Adetimilehin àti Adewumi Gbadamosi to jẹ́ babaláwo nítorí wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó pa ọmọdé kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ni Kehinde nítòsí ilé ìwòsàn ni Osogbo.
Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun, Wale Olokode sọ pé lẹ́yìn tí àwọn ará ìlú tá àwọn lólobó ni àwọn mú àwọn afurasi náà ni agbègbè Oke Ayepe Osogbo àti Kajola Ijesha.
"Wọn mú àwọn afunrasí pẹ̀lú ọwọ àti ẹsẹ̀ ẹnikan tí wọ́n pé ní Kehinde tó sì ti ń jẹrà, kò sí ẹni tó ti mọ orúkọ bàbá rẹ̀ àti àdúgbò tó ń gbé títí di àsìkò yìí.
Olórí àwọn afunrasí náà, Adewumi Gbadamosi, jẹ́wọ́ pé òun hùwà ìbàjẹ́ náà pẹ̀lú àlàyé pé òun gbé orí olóògbé náà fún Olagunju Adetunji fún ètùtù, gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà ọlọ́pàá ṣe sọ.
Gbadamosi sọ fún àwọn oníròyìn pé, òun yin Kehinde ní ìbọn lásìkò tó ń ṣe iṣẹ́ ọdẹ lóru ni Osogbo, ó fi kún pé lẹ́yìn tí òun yín ní ìbọn tán, òun pín ẹ̀yà ara rẹ̀, mú èyí tí oun nílò, tó sì ju èyí tó kù sínú odò.
Baba aláwo tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún ṣàlàyé pé òun gbé orí nàá fún Adetunji àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ Saka, tí wọ́n tí kàn sí òun tẹ́lẹ̀ láti rán wọn lọ́wọ́ láti ni ọ̀pọ̀ oníbàárà.
Bákan náà ló fi kún pé Ajani tí ó jẹ́ ọlọ́dẹ ran òun lọ́wọ́ láti gbé ọkùnrin tó pá lẹ́yìn tí òun paa tán.