Epe Fish Market: Wá wo oríṣi ẹja tí o rírí lọ́jà ẹja tó tóbi jùlọ ní Nàíjíríà

Yoruba ni ẹni ti ko ba de oko baba ẹlomiran ri, ni yoo ni oko baba toun lo tobi ju.

Bẹẹ ni ọrọ ri ni ọja ẹja ni Epe nibi ti oniruuru ẹja wa, pẹlu orukọ to le ni aadọta.

Lara awọn ẹja to wa nibẹ ni Ọsan, Ekuya, Owere, Ede, Salaporẹ, Kuta, Epiya, Ofan, Safu, Igangan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, ẹnu ko gba iroyin nigba ta foju kan awọn ẹja miran ti ori wọn to ti ọmọ tuntun.

Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ọpọ awọn apẹja yii, ti obinrin wa ninu wọn salaye awọn ipenija ti wọn n koju lẹnu isẹ naa.

Lara rẹ ni owo gege to n gun ori awọn ati ọkọ oju omi ti wọn fi n pa ẹja.

Ẹnu ko gba iroyin, ẹni to ba de ibẹ lo le sọ, ẹ ba wa kalọ silu Epe lati foju gan ni ohun ta n sọ.