Sunday Igboho: N kò fẹ́ oyè ọ̀gá àgbà páta fún ikọ̀ Amotekun nílẹ̀ Yorùbá

Nigba to n fesi lori ahesọ ọrọ naa fun awọn akọroyin, ti BBC Yoruba wa lara wọn, Sunday Igboho ni oun ko fẹ ipo oludari patapata fun ikọ Amotekun yika ilẹ Yoruba, ti wọn n yọ ọ naa.

O ni oun to jẹ oun logun bayii ni bi awọn ọdaran Fulani yoo se fi ilẹ Yoruba silẹ, ti alaafia yoo si jọba pada.