You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Covid19 Benefit: Àsìkò Coronavirus yìí jẹ́ kí n di télọ̀ tó mọṣẹ́ gidi - Favour
Ko tilẹ to pe ọdun mẹwaa rara ni Favour ti maa n lọ ba awọn obi rẹ pe oun fẹ kọ iṣẹ ranṣọranṣọ.
Ṣe awọn agba maa n sọ pe "Ọmọ tí yóò bá ti ṣe ṣámú ṣámú, àti kékére la ti ń mọ̀", Favour Adebayo wa ni ipele keji ileewe girama (JSS 2) ṣugbọn ọgbọn to wa lori rẹ ju ti kilaasi to wa lọ.
"Lati kekere ni mo ti maa n ran aṣọ fun bebi mii. Ọjọ́ tí mo sọ fún àwọn òbí mi pé mo fẹ kọ iṣẹ teelọ, wọn ni ki n duro di ọdun mẹwaa".
- Wọ́n ti yìnbọn pa olórí ẹgbẹ́ jàndùkú ''One Million Boys'' ní Ibadan’
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọmọogun Nàìjíríà tó lé ní 350 fẹ́ kọ̀we fi iṣẹ́ sílẹ̀?
- 'Báyìí la ṣe rìn ín láti pápákọ̀ òfurufú Abuja sí Eko bí ìrìnà òfurufú abẹ́lé ṣe bẹ̀rẹ̀'
- Ẹ́ wo bí sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ yìí ṣe ń fi ara rẹ̀ kọ́ àwọ́n òbinrin ní ìgbádùn ìbálòpọ̀
Nigba to pe ọmọ ọdun mẹwaa, wọn ko si kọ si i lẹnu, wọn jẹ ko bẹrẹ iṣẹ to yan laayo - Ṣebi ori lo mọ iṣ aṣela.
"Mo nifẹ iṣẹ ranṣọ ranṣọ gaaan". Favour ni inu oun dun si anfani toun ni lasiko Covid19 yii.
"Inú mi dùn pé Coronavirus jẹ́ kí wọn ti iléèwé pa. Lásìkò Coronavirus yìí, mo ti rán aṣọ púpọ̀ mo dẹ̀ ti pawó gan"
Ẹwẹ oun naa gbagbọ pe gbogbo nkan ti eeyan ba n ṣe laye, o gbọdọ fi iwe kun un.
"Lọ́jọ́ 'wájú, mo fẹ́ di ǹkan mẹ́ta, dókítà, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, ránṣọ-ránṣọ".