Wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ mi láti ṣèmọ́tótó ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ní Coronavirus

Àkọlé fídíò, Wọ́n nílò ìrànlawọ́ mi láti ṣèmọ́tótó ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn tó ní Coronavirus

Damoah Asare n ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbalẹ nile iwosan kan ni London.

O si n ṣiṣẹ ni ẹka ibi ti wọn ti n tọju awọn to ni arun Coronavirus ni ile iwosan Royal Free to wa ni Whitechapel.

Nigba ti o kọkọ bẹrẹ iṣẹ ni ẹka naa, ẹru ma n baa pe o ṣeeṣe ki oun naa lugbadi arun Coronavirus.

Ṣugbọn ni bayii, o ti ṣetan lati maa ba iṣẹ rẹ lọ ati lati koju arun ọrun.