Coronavirus cure: Akeugbagold sọ àṣírí ohun tí àrùn coronavirus ń dá lárà fáwọn pásítọ̀, àfáà àti ẹlẹ́sìn àbáláyé

Laipẹ yii ni eekan oniwaasi ni, Akeugbagold bọ lọwọ wahala awọn ajinigbepawo kan ti wọn ji awọn ọmọ rẹ gbe.

Amọṣa ninu ifọrọwerọ yii pẹluu, kii ṣe ọrọ awọn ibeji rẹ ti wọn ji gbe lo ba BBC News Yoruba sọ bikoṣe ọwọja arun coronavirus to gbaye kan bayii ninu ilana ẹsin lagbaye.

Gẹgẹbi o ṣe sọ, arun naa ti ṣi aṣọ loju ọpọ lati mọ Ọlọrun wn funrawọn.