GRIDCo: Àpọ̀jù iná mọ̀nàmọ́ná ló sọ Ghana sí òkùnkùn birimù

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ṣaadede ni awọn waya to gbe ina lọ si Mali bẹrẹ si ni gbona ti wọn si da ina ọhun pada si ori ibudo amunawa Ghana.

Ile iṣẹ eleto ina ọba nilẹ Ghana, Ghana Grid Company(GRIDCo) sọ pe aisina lawọn agbegbe kan lorileede Ghana ko ṣẹyin apọju ina to pada si ori opo nilẹ naa ti o si mu ki awọn ẹrọ amunawa dakẹ iṣẹ.

Ọga agba GRIDCo, Jonathan Amoako Baah ṣalaye pe niṣe ni aisina yi waye nigba ti ina ti wọn fi ranṣẹ si orileede Côte d'Ivoire pada si ori opo ina ti ilẹ Ghana.

Orileede Ghana n ta to ọgọrun Megawatts ina ọba ninu ina ti wọn n pese lati ibudo amunawa wọn fun orileede Côte d'Ivoire.

Ṣe ni awọn waya to gbe ina lọ si Mali bẹrẹ si ni gbona ti wọn si da ina ọhun pada si ori ibudo amunawa Ghana.

Ileeṣẹ eleto ina ọba Ghana fi ikede yi soju opo ayelujara wọn lati tọrọ aforijin lọdọ ara ilu.

Ninu atẹjade naa ti ọga ileeṣẹ naa Amoako Baah fọwọ si,wọn ni "Iṣẹlẹ naa kọja agbara wa ṣugbọn kete ti a ba ti yanju rẹ nia o da ina pada si awọn agbegbe ti ọrọ naa kan.''

Niṣe lawọn ọmọ ilẹ Ghana gba ori opo ayelujara lọ lati fi ẹhonu han nitori ina ọba ti ko si fun wakati mẹrinlelogun yii.