You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kogi, Bayelsa Governorship Elections: INEC kéde ọjọ́ tuntun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti kede ọjọ tuntun fun eto idibo sipo gomina ti yoo waye nipinlẹ Kogi ati Bayelsa.
Eto idibo naa to yẹ ko waye l'ọjọ keji, oṣu Kọkanla, ọdun 2019, ni yoo waye bayii lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, 2019.
INEC kede ọjọ tuntun naa lori opo ayelujara Twitter rẹ.
Ajọ INEC sọ pe sisun ti wọn sun eto idibo naa siwaju ko ṣẹyin bi ijọba ipinlẹ Bayelsa, ati awọn ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ, to fi mọ awọn olori ẹsin, ṣe kọwe ẹbẹ si ajọ naa lati sun un siwaju nitori pe ọjọ ti wọn kọkọ da fun idibo jẹ ọjọ kan naa pẹlu eto idupẹ ọdọọdun ti wọn maa n ṣe ni ipinlẹ Bayelsa.