Kwara Election: Àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú náà ní gbígbá PDP kúrò ní Kwara ló jẹ àwọn lógún

Awọn ẹgbẹ oselu to to marundinlogoji lo ti korajọ pọ ni ipinlẹ Kwara, lati se atilẹyin alailẹgbẹ fun ẹgbẹ oselu APC, ko lee moke ninu ibo gomina nipinlẹ naa.

Awọn ẹgbẹ oselu naa, lasiko ti wọn n sepade pẹlu awọn akọroyin lati kede ipinnu wọn naa, wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ wọn lati di ibo wn fun oludije ibo gomina fẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Kwara, Abdulrazaq Abdulrahman.

Nigba to n ki awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ oloselu naa kaabọ nibi ipade akọroyin naa, alaga fẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Kwara, Bashir Bọlarinwa ni ohun to dara ni bawọn ẹgbẹ oselu naa se pinnu lati sugba oludije ipo gomina fẹgbẹ APC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ tiẹ naa, agbẹnusọ fun awọn ẹgbẹ ti imọ wọn sọkan naa, Oladele Oluseun naa kesi awọn ololufẹ ẹgbẹ wọn, lati se atilẹyin fun ẹgbẹ oselu APC ninu ibo gomina ọjọ Satide.

Lara awọn ẹgbẹ oselu to korajọ lati se atilẹyin fun ẹgbẹ APC ni ẹgbẹ oselu Kowa, PPN, ADC, NCP ati PDC sugbọn ẹgbẹ oselu Labour ko si lara awọn ẹgbẹ oselu to peju sibi ipade akọroyin naa.

Saaju nigba to n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, ni kete to gunlẹ si npapakọ ofurufu ilu Ilọrin, oludije fun ipo gomina labẹ egbe oselu Labour nipinlẹ Kwara, Comrade Issa Aremu sọ pe, egbe oun ati APC si n fọrọ jomitoro ọrọ lọwọ nipa idibo gomina ati tawon asofin ipinle Kwara to de tan.

Amọ ko sọ pato boya ẹgbẹ oselu Labour yoo juwọ silẹ fun ẹgbẹ oselu APC lati di gomina lasiko ibo ti yoo waye lọjọ Satide, sugbọn Arẹmu ni eyikeyi ninu oludije fẹgbẹ APC ati Labour to ba wọle, ko si eyi ti ko dara nibẹ.

Arẹmu ni " Ohun kan soso lo se pataki si wa, eyi si ni ba se gba ẹgbẹ oselu PDP kuro lori aleefa. Ati awa, ANRP ati APC si ni ọrọ wa Papọ.