Nigeria 2019 Elections: Akala ní APC kò tó bẹ́ẹ̀ láti yọ ọmọ òun nípò alága

Àkọlé fídíò, Nigeria 2019 Elections: Akala ní APC kò tó bẹ́ẹ̀ láti yọ ọmọ òun nípò alága

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, oludije gomina fun ẹgbẹ oselu ADP nipinlẹ Ọyọ, Ọtunba Adebayọ Akala figbe ta pe ti ẹgb oselu APC ba fi yọ ọmọ oun nipo, wọn kan fẹ da ija igboro sil ni.

Akala, to ni oun yoo jaa nija ni, tun salaye pe, ẹgbẹ oselu APC ko tẹle ofin pẹlu bi wọn se kede pe awọn ti yọ ọmọ oun nipo alaga ijọba ibilẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akala ni awọn eeyan Ogbomọsọ nikan lo lee yọ alaga ijọba nipo, kii se Kọmisọna kankan pẹlu afikun pe ki lo de to jẹ igba ti ọmọ oun kuro ni APC, ni tiẹ yatọ si ti ara yoku.

Alao Akala tun ni arifin nla ni bawọn eeyan kan se npariwo pe oun n sisẹ fun Seyi Makinde to jẹ oludije gomina fẹgbẹ PDP.