Ochanya: Àwọn èèyàn wọde láti bèrè ìdájọ fún ọmọ ọdún mẹtala ti wọn fipabalopọ

Ilé ẹjọ ní Makurdi tí ní kí wọ́n fi àwọn arákùnrin méjì kan sí àhámọ́ torí pé wọn fi'pa ba ọmọdébìnrin kan lò pọ̀.

Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ni olu ilu Naijiria l'abuja, ṣe ni awọn eeyan wọde lọjọ kẹẹdọgbọn osu kẹwa lati bere idajọ fun ọmọ ọdun metala Ochanya Ogbanje ti wọn fipa ba lo pọ.
Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ni ile iwọsan ikọni ipinlẹ Benue ni Ochanya ti gbẹmi mi latari bi awọn okunrin meji kan ṣe fipa ba a lo pọ ti o si fa aisan oju ara obirin ti wọn pe ni Vesicovaginal fistula (VVF) fun un.
Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ agbẹjọro obinrin, FIDA ati iya ọmọ naa ni wọn gbe ẹjọ Ochanya lo si agọ ọlọpaa. Lẹyin iwaadi ,awọn ọlọpaa mu Baba ati ọmọ rẹ okunrin ti wọn jijọ fipa ba Ochanya lo pọ.
Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ọjọ kọkandinlogun osu kẹwa ni Ochanya papoda ni ile iwosan ikọni to wa ni Makurdi.
Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Ọpọ eeyan to fi mọ awọn akẹkọ jade ni ile iwe Federal Government Girl's College Gboko lati kọwọrin lọ fi ẹhonu han ni ilu Abuja
Aworan awọn oluwọde
Àkọlé àwòrán, Igbe ẹ yẹ'gi fun wọn lawọn oluwọde n ke ti wọn si ni ki ijọba da si ọrọ to wa nilẹ yii