Ibe Kachikwu ,Mínísítà fún epò rọ̀bì sọ pé òun kò parọ́ ìwé ẹ̀rí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Àṣìwí kò tó àṣìsọ l'ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ nípa mínísítà kejì fún epo rọ̀bì Nàìjíríà, Ibe Kachukwu, tí ìwé ìròyìn kan sọ wí pé ó parọ́ nípa irú ìwé ẹ̀rí tó gbà jáde ni yunifásitì.

Ibe Kachikwu ti fèsì wí pé òun kò parọ́ ìwé ẹrí, bí kò ṣe wi pé àwọn akọ̀ròyìn ṣi òun gbọ́ ní.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta l'ọ́jọ́bọ̀ lójú òpó Twitter, Kachikwu ṣàlàyé pé ohun tí òun sọ ni òun wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lákè nígbà tí òun parí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nípa òfin ná yunifásitì Nigeria, Nsukka.

" Ìwé ẹrí tó tẹ̀lé èyí tó tayọ jù ni mo gbà, tí òun ṣì wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe dáadáa jùlọ"

''Níbi ọrọ ti mo n bá àwọn ọ̀dọ́ sọ níbi ayẹyẹ ilé ìjọsìn Commonwealth of Zion,ohun ti mo sọ ni wí pé mo wà lára àwọn tó l'eke.Ìdí tí mo ṣì fi sọ bẹẹ ni lati ṣe ìwúrí fún àwọn ọ́dọ́, ki wọ́n baa le ṣe dáadáa níbi ẹ̀kọ́ wọn''

Ó tèsíwájú pé nigba ti òun wa ni ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin l'ọ́dún 1979 ''èmi ni mo tayọ láàrin àwọn tí a jọ wà ní kíláàsì kan na.''

''L'ọ́dún ta n wí yí, àmì ẹyẹ márùn ni mo gbà nínú méje tí ilé ẹ̀kọ́ náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́.''

Ó sọ pé ''kò sí ohun tó jọ ìwé ẹ̀rí tó tayọ jù lọ l'ọ́dún náà, ṣùgbọ́n ìwé ẹ̀rí tí mo gbà ṣe déédéé kí èèyàn gba ìwé ẹ̀rí tó tayọ l'óde òní.''

Tí a kò bá gbàgbé, mínísítà méjì nínú ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari ni wọ́n ti fi ẹ̀sùn kàn nípa ìwé ẹ̀rí ìsìnrú ìlú ètò àgùnbánirọ̀, NYSC.