AMVCA 2018: Ọdunlade Adekọla, Fẹmi Adebayọ, àtàwọn míì gba àmì ẹ̀yẹ

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òṣèré Yorùba ló bá àwọn akẹgbẹ́ wọn tó kù nílẹ̀ Afrika péjọ níbi àmì ẹ̀yẹ AMVCA.

Ogbontarigi òṣèré, Femi Adebayo
Àkọlé àwòrán, Femi Adebayo nínú Sinima Etiko Onigedu
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @Femi Adebayo

Àkọlé àwòrán, Wọ́n yan òṣèré Femi Adebayo pẹ̀lú bàbá rẹ̀, Adebayo Salami fún àmì ẹ̀yẹ yìí sùgbọ́n bàbá ti sọ fún ọmọ rẹ̀ nílé pé kó lọ mú òun orí òun wú, Femi náà sì ló pegedé
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @bammybestowed

Àkọlé àwòrán, Ẹnu kò sìn lára Bambam tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdíjé Big Brother Naija l'ọ́dún 2018 nítorí aṣọ aláràmbarà tó wọ́
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @lagosalabaru.j...

Àkọlé àwòrán, Ọdunlade Adekọla gba àmì ẹ̀yẹ òṣèrékùnrin tó tayọ jù nínú eré apanilẹ́rìín fún ipa tó kó nínú eré 'A Million Baby'
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @Toyin Abraham

Àkọlé àwòrán, Toyin Abraham kò gba àmì ẹ̀yẹ lọ́dún yìí sùgbọ́n ó wà lára àwọn tó dárúkọ àwọn tó gba àmì ẹ̀yẹ
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @lagosalabaru

Àkọlé àwòrán, Gbajúgbajà òṣèrè apanilẹ́rìín tó tún jẹ́ olórin, Folarin Falana tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Falz naa gba àmi ẹ̀yẹ́
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @Fathia Williams

Àkọlé àwòrán, Àwòmáleèlọ́ ni aṣọ tí òrékelẹ̀wà òṣèré yìí, Fathia Williams wọ̀ lọ̀ síbi àmì ẹ̀yẹ ọ̀hún
Alaraburada

Oríṣun àwòrán, @tailor_001

Àkọlé àwòrán, Onífọ́tò yàmí tùka-tùka, aṣọ ọ mi tó, ó tún yọ abùradà
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @thelotachukwu

Àkọlé àwòrán, Lota Chukwu, ọkan lára àwọn òṣèré nínú eré àgbéléwò Jenifa's Diary náà kò gbẹ́yìn
Àwọn àwòrán láti Africa Magic Viewers Choice Awards

Oríṣun àwòrán, @iamnino_b

Àkọlé àwòrán, Èyí o wa jojú ní gbèsè bí Bolanle Ninalowo, oṣèrè fíìmù Yoruba àti lédè Òyìnbo ṣe dúró déédé l'ọ́mọkùnrin níbi àmì ẹ̀yẹ náà
Gbọngan

Oríṣun àwòrán, @airtelnigeria

Àkọlé àwòrán, Bámúbámú ni gbọ̀ngàn Eko Hotel and Suites, Victoria Island, kún fún èérò
Melaye ati abaribe

Oríṣun àwòrán, @dinomelaye

Àkọlé àwòrán, Ṣẹ́nétọ̀ Dino Melaye gan an l'óun kò gbọdọ̀ máà débẹ̀. Òun àti Ṣẹ́nétọ̀ Enyinnaya Abaribe láti ìpínlẹ̀ Anambra ló jọ lọ f'ójú ní oúnjẹ ayọ̀