Àwòràn ọdún egúngún ilu Ìwó jẹ́ àwòpadà-sẹ́yìn

Àwọn àwòrán yìí ló jẹ ojú ní gbèsè nípa ọdún egúngún 2018 tó wáyé ní ìlú Ìwó.

Egungun kan
Àkọlé àwòrán, O gbẹnu tan fun egungun to n lo irukẹrẹ bii ọba
Awọn egungun to n jo
Àkọlé àwòrán, Ibadi egungun yii dara nijo
Awọn ero to n woran egungun ati egungun
Àkọlé àwòrán, Ọdọ lo n gbe egungun ni abi agba ?
Awọn ero to n woran egungun
Àkọlé àwòrán, Ẹni ti ko lee rin ni ki wọn gbe oun lasiko ọdun egungun ilu Iwo.
Egungun kan
Àkọlé àwòrán, Ẹku oni leesi, fun eegun igbalode la ba pe ẹku yii
Awọn ero to n woran egungun ati egungun
Àkọlé àwòrán, Egungun alare ree o pẹlu ilu ati ijo to sọkutu-wọwọ
Awọn ero to n woran egungun ati egungun
Àkọlé àwòrán, Egungun ọlọmọ yọyọ ree, n se lo ko ọmọ yọyọ sẹyin
Awọn ero to wa lẹyin egungun pẹlu atori lọwọ
Àkọlé àwòrán, Ẹni to ba gba pasan meji sara ninu awọn pasan yii, yoo wa ibi wọ si ni
Ọmọdekunrin kan to mu atori lọwọ
Àkọlé àwòrán, Ẹni to ba sẹ ọmọde yii, ko tete ba ẹsẹ rẹ sọrọ, atori yii lee mu ki gende bu sẹkun
Awọn ero to wa lẹyin egungun pẹlu atori lọwọ
Àkọlé àwòrán, Ẹgan ni ẹ, awon eeyan woran ọdun eegun 2018 nilu Iwo
Awọn ero to n woran egungun ati egungun
Àkọlé àwòrán, Tilu-tifọn ni awọn eeyan ilu Iwo fi ki awọn ara ọrun kaabọ
Awọn obinrin to n wọ tẹle egungun lẹyin pẹlu ọrẹ ni ọwọ wọn
Àkọlé àwòrán, Awọn obinrin gan ja ọrẹ lasiko ọdun eegun ọdun yii
Ọmọkunrin kan to gbe odo lori lẹyin eegun
Àkọlé àwòrán, Ara meriri ma tun leyi, ewo ni ti odo lẹyin egungun