Àyájọ́ Ibà: Ònà àbáyọ sí ikú ọmọdé àt'àgbà lásìkó yìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Òní tí ń ṣe àyájọ́ ọ́jọ̀ àìsàn ibà, jẹ́ ọjọ́ àkíyèsi.
Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kan nínú ètò ìlera làti fásitì Obafemi Awolowo, Ile-Ife, Ọjọ̀gbọ́n Adedeji Onayade, sọ pé a ti ń sún mọ́ òpin àìsàn ibà ní Naijiria, ṣùgbọ́n, a ní láti ṣe àwọn ìṣọ́ra kọ̀ọ̀kan.
Ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣàlàyé pé a gbọ́dọ̀ ri i pé àwọn aláboyún àti ọmọ ọwọ́ sí ọdún márùń un gbọ́dọ̀ máa lo àwọ̀n ẹ̀fọn tí wọ́n fi òògùn tó ń pa kòkòrò sí tí wón bá ti fẹ́ sùn.
Mínísítà fún èto ìlera ní orílẹ́-èdè Naijiria ọ̀jọ̀gbọ́n Isaac Adewole sọ wí pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ayédèrú òògùn tí ó wà ní ìta ni ó ń fa ìkùna tí ó lágbára jù fún ipa láti mú òpin bá àìsàn ibà ní orílẹ̀-èdè yí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ibi tí iṣẹ́ dé dúró
Àjọ àgbáyé tí ó ń rí sí ìlera sọ wí pé àìsàn ibà ń pa ọmọdé kọ̀ọ̀kan ní ìṣẹ́jú méjìméjì. Mẹ́sàń nínú ènìyàn mẹ́wàá tí àìsàn ibà bá pa ni ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Afrika.
Ní orílẹ̀-èdè Naijiria, ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ìjọba tí ó ń rí sí ìlera sọ wí pé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn un ènìyàn ni àìsàn ibà ń bá jà.
Mínísítà Adewole sọ wí pé tí Naijiria bá kápá iba, àìsàn náà yóò fẹ́ẹ̀ tán ní Afrika.

Kí ló dé gan an, tí àìsàn ibà kò tíì lọ pátápátá láti igbà tí a ti ń ba a jà ní orílẹ̀ èdè Naijiria? Ọ̀jọ̀gbọ́n Onayade sọ wí pé àwọn ẹ̀fọn tí ó ń fa ibà ti ní agbára àtakò sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn òògùn ibà tó wà níta.
Sùgbọ́n ó gbà pé, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ǹkan ni a lè ṣe láti ríi pé àìsàn ibà lọ pátápátá.
Ohun tí ó yẹ ní ṣíṣe
- A gbọ́dọ̀ máà lo òògòn ibà tí wọ́n bá fún wa ní ilé ìwòsàn tán
- Kí a máa lo àpò ẹfọn
- A kò gbọ́dọ̀ fún ìdọ̀tí láàyè tàbí fi omi tó bá rẹgún sílẹ̀ ní àyíká ilé
- A ní láto máa lo àpapọ̀ òògùn bìi Artemether àti Lumefantrine - òògùn irú eyọkan kò làgbàra tó
Àwọn wo ni àìsàn ibà burújù lára wọn?
Ọ̀jọ̀gbọ́n Onayade ní àwọn aláboyún àti àwọn ọmọ ọwọ́ títí dé ọmọ ọdún márùń ni.
Ó ní àwọn wọ̀nyí ni àìsàn ibà máa ń ṣe ikú pa ní ọdọọdún jù.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2
Àyájọ́ ọjọ́ àìsàn ibà ló máa ń wáyé ní ọjọ́ karùndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin ní ọdọọdún.
Ní ti ọdún yìí, bí a ṣe lè dópin àìsàn náà ni ó gbayé kan, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ń fi èró ọkan wọn hàn lórí àìsàn náà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

End of X post, 4